3
Ẹ̀rí jíjẹ́ nípa àwọn ọmọ Israẹli 
 
1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli nípa àwọn ìdílé tí mo mú jáde láti Ejibiti:   
2 “Ìwọ nìkan ni ẹni tí mo yàn  
nínú gbogbo àwọn ìran ayé yìí;  
nígbà náà èmi ó jẹ ọ́ ní yà  
fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”   
   
 
3 Ẹni méjì ha à le rìn pọ̀  
láìjẹ́ pé wọ́n ti pinnu láti ṣe bẹ?   
4 Ǹjẹ́ Kìnnìún yóò ha bú ramúramù nínú igbó,  
bí kò bá ní ohun ọdẹ?  
Ọmọ kìnnìún yóò ha ké jáde nínú ìhó rẹ̀  
bí kò bá rí ohun kan mú?   
5 Ǹjẹ́ ẹyẹ ṣubú sínú okùn ọdẹ lórí ilẹ̀  
nígbà tí a kò dẹ okùn ọdẹ fún un?  
Okùn ọdẹ ha lè hù jáde lórí ilẹ̀  
nígbà tí kò sí ohun tí yóò mú?   
6 Nígbà tí ìpè bá dún ní ìlú,  
àwọn ènìyàn kò ha bẹ̀rù?  
Tí ewu bá wa lórí ìlú  
kò ha ṣe Olúwa ni ó fà á?   
   
 
7  Nítòótọ́ Olúwa Olódùmarè kò ṣe ohun kan  
láìfi èrò rẹ̀ hàn  
fun àwọn wòlíì ìránṣẹ́ rẹ̀.   
   
 
8 Kìnnìún ti bú ramúramù  
ta ni kì yóò bẹ̀rù?  
Olúwa Olódùmarè ti sọ̀rọ̀  
ta ni le ṣe àìsọ àsọtẹ́lẹ̀?   
   
 
9 Ẹ kéde ní ààfin Aṣdodu  
àti ní ààfin ní ilẹ̀ Ejibiti.  
“Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè ńlá Samaria;  
kí ẹ sì wo ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láàrín rẹ̀  
àti ìnilára láàrín àwọn ènìyàn rẹ.”   
   
 
10 “Wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe rere,” ni Olúwa wí,  
“àwọn ẹni tí ó gba àwọn ìwà ipá àti olè sí ààfin rẹ̀.”   
11 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:  
“Àwọn ọ̀tá yóò pa ilẹ̀ náà run;  
yóò wó ibi gíga yín palẹ̀  
a ó sì ba ààfin rẹ̀ jẹ́.”   
12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:  
“Bí olùṣọ́-àgùntàn ti ń gbà itan méjì  
kúrò ní ẹnu kìnnìún tàbí ẹ̀là etí kan  
bẹ́ẹ̀ ni a ó mú àwọn ọmọ Israẹli,  
tí ń gbé Samaria kúrò  
ní igun ibùsùn wọn  
ní orí àga ìrọ̀gbọ̀kú wọn ní Damasku.”   
13 “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.   
14 “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,  
Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run;  
ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò  
yóò sì wó lulẹ̀.   
15 Èmi yóò wó ilé òtútù  
lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru;  
ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé  
a ó sì pa ilé ńlá náà run,”  
ni Olúwa wí.