17
+Ẹ má ṣe fi màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù, tàbí àbàwọ́n rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí ìríra ni èyí yóò jẹ́ fún un.
+Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó ń gbé láàrín yín ní èyíkéyìí ìlú wọ̀n-ọn-nì, tí Olúwa fún un yín bá ń ṣe ibi ní ojú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ríré májẹ̀mú rẹ̀ kọjá, èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, tí èyí sì dé etí ìgbọ́ ọ yín, kí ẹ wádìí ọ̀rọ̀ náà dájúdájú. Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ tí ó sì hàn gbangba pé ó ti ṣe ohun ìríra yìí, ní Israẹli. Ẹ mú ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ti ṣe ibi yìí wá sí ẹnu-ọ̀nà ibodè ìlú u yín, kí ẹ sọ ọ́ ní òkúta pa. +Lénu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípasẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo. +Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárín yín.
Àwọn ilé ẹjọ́
Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ èyí tí ó nira jù láti dá, yálà ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù, ẹ mú wọn lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Lefi, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́. 10 Kí ìwọ kí ó sì ṣe bí ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ti àwọn ará ibi tí Olúwa yóò yàn náà yóò fihàn ọ, kí ìwọ kí ó sì máa kíyèsí àti máa ṣe gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí wọn kọ́ ọ. 11 Ẹ ṣe bí òfin tí wọ́n kọ́ ọ yín, àti ìpinnu tí wọ́n fún un yín. Ẹ má ṣe yípadà sọ́tùn tàbí sósì, kúrò nínú ohun tí wọ́n sọ fún un yín. 12 Ọkùnrin náà tí ó bá ṣe àìbọ̀wọ̀ fún adájọ́ tàbí àlùfáà tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run yín, níbẹ̀ ni kí ẹ pa á. Nípa báyìí ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní Israẹli. 13 Gbogbo ènìyàn ni yóò sì gbọ́, ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n, wọn kò sì ní ṣe àìgbọ́ràn mọ́.
Ọba
14 Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò fún un yín, tí ẹ sì ti gba ilẹ̀ náà, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ sì wá sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a yan ọba tí yóò jẹ lé wa lórí bí i ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká.” 15 Ẹ rí i dájú pé ọba tí Olúwa Ọlọ́run yín yàn fún un yín ní ẹ yàn. Ó gbọdọ̀ jẹ́ láàrín àwọn arákùnrin yín. Ẹ má ṣe fi àjèjì jẹ ọba lórí i yín: àní ẹni tí kì í ṣe arákùnrin ní Israẹli. 16 Síwájú sí i, ọba náà kò gbọdọ̀ kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin jọ fún ara rẹ̀, tàbí kí ó rán àwọn ènìyàn náà padà sí Ejibiti láti wá àwọn ẹṣin sí i, nítorí pé Olúwa ti sọ fún un yín pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ tún padà lọ ní ọ̀nà náà mọ́.” 17 Kò gbọdọ̀ kó aya jọ, kí ọkàn rẹ̀ má bá a yapa kúrò. Kò gbọdọ̀ kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara rẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀.
18 Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó ṣe àdàkọ àwọn òfin wọ̀nyí sí inú ìwé fún ara rẹ̀, láti inú ti àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi. 19 Èyí yóò sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀, òun ó sì máa kà nínú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, láti máa tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí àti àwọn ìlànà rẹ̀ tọkàntọkàn. 20 Kí ó má ba à lérò pé òun sàn ju àwọn arákùnrin rẹ̀ yòókù lọ, kí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ yípadà kúrò nínú òfin wọ̀nyí sí ọ̀tún tàbí sí òsì. Bẹ́ẹ̀ ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ ọba pẹ́ títí ní Israẹli.
+ 17:1 Le 22.17-24. + 17:2 Ek 22.20. + 17:6 Nu 35.30; De 19.15; Mt 18.16; 2Kọ 13.1; 1Tm 5.19; Hb 10.28. + 17:7 De 19.19; 1Kọ 5.13.