27
Pẹpẹ ní orí òkè Ebali
Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́. Nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani sí inú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbé kalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun. Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ. Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun. Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn. Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ. Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”
Ègún ní orí òkè Ebali
Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí. 10 Gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”
11 Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.
12 Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini. 13 Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.
14 Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè:
 
15 +“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
16 +“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
17 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
18 +“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
19 +“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
20 +“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
21 +“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
22 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
23 +“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
24 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
25 “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
26 +“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.”
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”
+ 27:15 Ek 20.4,23; 34.17; Le 19.4; 26.1; De 4.16,23,25; 5.8; 7.25. + 27:16 Ek 20.12; 21.15,17; Le 20.9; De 5.16; 21.18-21. + 27:18 Le 19.14. + 27:19 Ek 22.21-24; 23.9; Le 19.33,34; De 24.17,18. + 27:20 Le 18.8; 20.11; De 22.30. + 27:21 Ek 22.19; Le 18.23; 20.15. + 27:23 Le 18.17; 20.14. + 27:26 Ga 3.10.