33
Mose bùkún fún àwọn ẹ̀yà
1 Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú.
2 Ó sì wí pé,
“Olúwa ti Sinai wá,
ó sì yọ sí wọn láti Seiri wá
ó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá.
Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wá
láti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá.
3 Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀,
gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀.
Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀,
àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,
4 òfin tí Mose fi fún wa,
ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu.
5 Òun ni ọba lórí Jeṣuruni
ní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀,
pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli.
6 “Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú,
tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”
7 Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda:
“Olúwa gbọ́ ohùn Juda
kí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.
Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,
kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!”
8 Ní ti Lefi ó wí pé,
“Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wà
pẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.
Ẹni tí ó dánwò ní Massa,
ìwọ bá jà ní omi Meriba.
9 Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,
‘Èmi kò buyì fún wọn.’
Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,
tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,
ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.
10 Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀
àti Israẹli ní òfin rẹ̀.
Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀
àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.
11 Bùsi ohun ìní rẹ̀, Olúwa,
kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;
àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,
kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”
12 Ní ti Benjamini ó wí pé,
“Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,
òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,
ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.”
13 Ní ti Josẹfu ó wí pé,
“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,
fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrì
àti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;
14 àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá
àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
15 pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanì
àti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
16 Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀
àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.
Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,
lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀.
17 Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;
ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.
Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,
pàápàá títí dé òpin ayé.
Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá Efraimu,
àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Manase.”
18 Ní ti Sebuluni ó wí pé,
“Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ,
àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ.
19 Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkè
àti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,
wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun,
nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”
20 Ní ti Gadi ó wí pé,
“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!
Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,
ó sì fa apá ya, àní àtàrí.
21 Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;
ìpín olórí ni a sì fi fún un.
Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,
ó mú òdodo Olúwa ṣẹ,
àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.”
22 Ní ti Dani ó wí pé,
“Ọmọ kìnnìún ni Dani,
tí ń fò láti Baṣani wá.”
23 Ní ti Naftali ó wí pé,
“Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́run
àti ìbùkún Olúwa;
yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.”
24 Ní ti Aṣeri ó wí pé,
“Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri;
jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀
kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.
25 Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,
agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.
26 “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni,
ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ
àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀.
27 Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,
àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.
Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ,
ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’
28 Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà,
orísun Jakọbu nìkan
ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,
níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.
29 Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli,
ta ni ó dàbí rẹ,
ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?
Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀
àti idà ọláńlá rẹ̀.
Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ,
ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”