10
1 Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú,  
bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.   
2 Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà,  
ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.   
3 Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà,  
òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n  
a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.   
4 Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,  
ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀;  
ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá.   
   
 
5 Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,  
irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.   
6 A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ,  
nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ.   
7 Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,  
nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.   
   
 
8 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;  
ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.   
9 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;  
ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.   
   
 
10 Bí àáké bá kú  
tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n;  
yóò nílò agbára púpọ̀  
ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.   
   
 
11 Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,  
kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.   
   
 
12 Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́  
ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnra rẹ̀ ni yóò parun.   
13 Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;  
ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.   
14 Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀.  
   
 
Kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀  
ta ni ó le è sọ fún un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?   
   
 
15 Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá a lágara  
kò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìlú.   
   
 
16 Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀  
àti tí àwọn ọmọ-aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.   
17 Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọlọ́lá,  
àti tí àwọn ọmọ-aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,  
fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmutípara.   
   
 
18 Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jì  
bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.   
   
 
19 Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àsè fún,  
wáìnì a máa mú ayé dùn,  
ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo.   
   
 
20 Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,  
tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ibùsùn rẹ,  
nítorí pé ẹyẹ ojú ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ  
ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.