16
Òwe nípa àìṣòdodo Jerusalẹmu
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, mú kí Jerusalẹmu mọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀. +Sọ pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí Jerusalẹmu, ìran rẹ àti ilẹ̀ ìbí rẹ wà ní ilẹ̀ Kenaani; ará Amori ni baba rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì jẹ́ ará Hiti. Ní ọjọ́ tí a bí ọ, a kò gé okùn ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì fi omi wẹ̀ ọ́ láti mú kí o mọ́, a kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára rárá, bẹ́ẹ̀ ni a kò fi aṣọ wé ọ. Kò sí ẹni tó ṣàánú tàbí kẹ́dùn rẹ dé bi à ti ṣe nǹkan kan nínú ìwọ̀nyí fún ọ, ṣùgbọ́n lọ́jọ́ ìbí rẹ, ìta la jù ọ́ sí torí wọ́n kórìíra rẹ.
“ ‘Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, “Yè!” Nítòótọ́, nígbà tí ìwọ wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé, “Yè.” Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòhò láìfi nǹkan kan bora.
“ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ̀ẹ́ rẹ ti tó, mo fi ìṣẹ́tí aṣọ mi bo ìhòhò rẹ. Mo búra fún ọ, èmi sì bá ọ dá májẹ̀mú ìwọ sì di tèmi, ni Olúwa Olódùmarè wí.
“ ‘Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò ní ara rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára. 10 Mo fi aṣọ oníṣẹ́-ọnà sí ọ lára láti wọ̀ ọ́, mo wọ bàtà aláwọ fún ọ. Mo fi aṣọ funfun gbòò àti aṣọ olówó iyebíye ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́. 11 Mo fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà ọwọ́ sí ọ ní ọwọ́, mo fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn sí ọ ní ọrùn, 12 mo sì tún fi òrùka sí ọ ní imú, mo fi yẹtí sí ọ ní etí, mo sì fi adé tó rẹwà dé ọ ní orí. 13 Báyìí ni mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà; tí aṣọ rẹ jẹ́ funfun gbòò, aṣọ olówó iyebíye àti aṣọ tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí. Ìyẹ̀fun kíkúnná, oyin àti òróró ni oúnjẹ rẹ. Ó di arẹwà títí ó fi dé ipò ayaba. 14 Òkìkí rẹ sì kàn káàkiri orílẹ̀-èdè nítorí ẹwà rẹ, nítorí dídán tí mo fi ṣe ẹwà rẹ ní àṣepé, ni Olúwa Olódùmarè wí.
15 “ ‘Ṣùgbọ́n, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, ìwọ sì di alágbèrè nítorí òkìkí rẹ. Ìwọ sì fọ́n ojúrere rẹ káàkiri sí orí ẹni yówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ. 16 Ìwọ mú lára àwọn aṣọ rẹ, láti rán aṣọ aláràbarà fún ibi gíga òrìṣà tí ìwọ ti ń ṣe àgbèrè. Èyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá. 17 Ìwọ tún mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ dáradára tí mo fi wúrà àti fàdákà ṣe fún ọ láti fi yá ère ọkùnrin tí ó ń bá ọ ṣe àgbèrè papọ̀. 18 Ìwọ sì wọ aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ rẹ fún wọn, o sì tún gbé òróró àti tùràrí mi sílẹ̀ níwájú wọn. 19 Ìwọ tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ—ìyẹ̀fun dáradára, òróró àti oyin—fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni Olúwa Olódùmarè wí.
20 “ ‘Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rú ẹbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà. Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí? 21 Tí ìwọ ti pa àwọn ọmọ mí, ìwọ sì fà wọ́n fún ère gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun. 22 Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbèrè rẹ, ìwọ kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tí ìwọ wà ní ìhòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀.’
23 “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ‘Ègbé! Ègbé ni fún ọ. Lẹ́yìn gbogbo ìwà búburú rẹ, 24 ìwọ kọ́lé amọ̀ fún ara rẹ, ìwọ sì kọ́ ojúbọ gíga sí gbogbo òpin ojú pópó. 25 Ní gbogbo ìkóríta ni ìwọ lọ kọ ojúbọ gíga sí, tí ìwọ sọ ẹwà rẹ di ìkórìíra, ìwọ sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ nípa fífi ara rẹ sílẹ̀ fún gbogbo ẹni tó ń kọjá lọ. 26 Ìwọ ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú ará Ejibiti tí í ṣe aládùúgbò rẹ láti mú mi bínú ìwọ sì ti sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀. 27 Nítorí náà ni mo fi na ọwọ́ mi lé ọ lórí, mo sì ti bu oúnjẹ rẹ̀ kù; èmi yóò sì mú ìfẹ́ àwọn to kórìíra rẹ ṣẹ́ lé ọ lórí, àwọn ọmọbìnrin Filistini ti ìwàkiwà rẹ tì lójú. 28 Nítorí àìnítẹ́lọ́rùn rẹ, ìwọ ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú ara Asiria; ìwọ ti bá wọn ṣe àgbèrè, síbẹ̀síbẹ̀, kò sì lè tẹ́ ọ lọ́rùn. 29 Ìwọ si ti sọ àgbèrè rẹ di púpọ̀ láti ilẹ̀ Kenaani dé ilẹ̀ Kaldea; síbẹ̀ èyí kò sì tẹ́ ọ lọ́rùn níhìn-ín yìí.’
30 Olúwa Olódùmarè wí pé, ‘Báwo ni ọkàn rẹ ṣe jẹ aláìlera tó tí o ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, bí iṣẹ́ àwọn agídí alágbèrè! 31 Ni ti pé ìwọ kọ́ ilé gíga rẹ ni gbogbo ìkóríta, tí ìwọ sì ṣe gbogbo ibi gíga rẹ ni gbogbo ìta, ìwọ kò sì wa dàbí panṣágà obìnrin, ní ti pé ìwọ gan ọ̀yà.
32 “ ‘Ìwọ alágbèrè aya! Ìwọ fẹ́ràn ọkùnrin àjèjì ju ọkọ rẹ lọ! 33 Àwọn ọkùnrin máa ń sanwó fún àwọn panṣágà ni ṣùgbọ́n ìwọ lo tún ń sanwó fun wọn, tí ó tún ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn àti owó ẹ̀yìn kí wọn bá à le máa wá ọ wá láti gbogbo agbègbè fún àgbèrè ṣíṣe. 34 Nínú àgbèrè rẹ ìwọ yàtọ̀ sí àwọn alágbèrè obìnrin yòókù; nínú àgbèrè rẹ tí ẹnìkan kò tẹ̀lé ọ láti ṣe àgbèrè; àti ní ti pé ìwọ ń tọrẹ tí a kò sì tọrẹ fún ọ, nítorí náà ìwọ yàtọ̀.
35 “ ‘Nítorí náà, ìwọ alágbèrè, gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa! 36 Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, “Nítorí pé ìwọ tú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ jáde, ìwọ sì fi ìhòhò rẹ hàn, nípa ṣíṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ rẹ, àti nítorí gbogbo òrìṣà ìríra tí o fi ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ṣe ìrúbọ fún, 37 nítorí náà, Èmi yóò ṣa gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ jọ, àwọn ẹni ti ìwọ ti bá jayé àti gbogbo àwọn tí ìwọ ti fẹ́ àti àwọn tí ìwọ kórìíra. Èmi yóò sa gbogbo wọn káàkiri jọ, láti mú wọn lòdì sí ọ, èmi yóò sí aṣọ rẹ, níwájú wọn, wọn yóò sì rí ìhòhò rẹ. 38 Èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti dá obìnrin tó ba ìgbéyàwó jẹ́, tí wọn sì ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀; Èmi yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ ìbínú àti owú mi wá sórí rẹ. 39 Nígbà náà ni èmi yóò fà ọ lé àwọn olólùfẹ́ rẹ lọ́wọ́, wọn yóò sì wó gbogbo òkìtì rẹ pẹ̀lú àwọn ojúbọ rẹ palẹ̀. Wọn yóò tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ ni wọn yóò gbà, wọn yóò sì fi ọ sílẹ̀ ní ìhòhò àti ní àìwọṣọ. 40 Wọn yóò pe àjọ ènìyàn jọ lé ọ lórí, àwọn tí yóò sọ ọ́ ní òkúta, tiwọn yóò sì fi idà wọn gé ọ sí wẹ́wẹ́. 41 Wọn yóò jo gbogbo ilé rẹ palẹ̀ wọn yóò sì fi ìyà jẹ ọ́ ní ojú àwọn obìnrin. Èmi yóò fi òpin sí àgbèrè ṣíṣe rẹ. Ìwọ kò sì ní san owó fún àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ́. 42 Nígbà náà ni ìbínú mi sí o yóò rọ̀, owú ìbínú mi yóò sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ; inú mi yóò rọ̀, èmi kò sì ní bínú mọ́.”
43 “ ‘Nítorí pé ìwọ kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé, Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sí orí rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí, ìwọ kì yóò sì ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí ni orí gbogbo ohun ìríra rẹ mọ́?
44 “ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.” 45 Ìwọ ni ọmọ ìyá rẹ ti ó kọ ọkọ rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀; ìwọ ni arábìnrin àwọn arábìnrin rẹ tí ó kọ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn: ara Hiti ni ìyá rẹ, ara Amori sì ni baba rẹ. 46 Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaria, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá àríwá rẹ, àti àbúrò rẹ obìnrin ní ń gbé ọwọ́ òsì rẹ̀, àti àbúrò rẹ obìnrin ti ń gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni Sodomu àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin. 47 Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà ìríra wọn ṣùgbọ́n ní àárín àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ 48  Olúwa Olódùmarè wí pé, “Bí mo ṣe wà láààyè, Sodomu tí í ṣe ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ kò ṣe to ohun tí ìwọ àti ọmọbìnrin rẹ ṣe.”
49 “ ‘Wò ó, ẹ̀ṣẹ̀ tí Sodomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ṣẹ̀ nìyìí. Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran tálákà àti aláìní lọ́wọ́. 50 Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti rò ó, nítorí ìgbéraga àti àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe. 51 Samaria kò ṣe ìdajì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe. 52 Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ. Nítorí náà rú ìtìjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo.
53 “ ‘Bi o tilẹ̀ jẹ pe èmi yóò mú ìgbèkùn wọn padà, ìgbèkùn Sodomu àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, pẹ̀lú Samaria àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, nígbà náà ni èmi yóò tún mú ìgbèkùn àwọn òǹdè rẹ wá láàrín wọn, 54 kí ó bá à le rú ìtìjú rẹ, àti ẹ̀gàn gbogbo ohun tí ìwọ ṣe láti tù wọ́n nínú. 55 Nígbà tí àwọn arábìnrin rẹ, Sodomu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ; Samaria àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ba padà si ipò tí wọn wà tẹ́lẹ̀, ìgbà náà ni ìwọ náà yóò padà sí ipò àtijọ́ rẹ. 56 Ìwọ ko tilẹ̀ ní dárúkọ arábìnrin rẹ Sodomu ni ọjọ́ ìgbéraga rẹ, 57 kó tó di pé àṣírí ìwà búburú rẹ tú síta, báyìí ìwọ di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Edomu, Siria àti gbogbo agbègbè rẹ, àti lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Filistini àti lọ́dọ̀ àwọn tó yí ọ ká, tiwọn si ń kẹ́gàn rẹ. 58 Èmi yóò gba ẹ̀san ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti àwọn iṣẹ́ ìríra rẹ ní Olúwa wí.’
59 “Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ‘Èmi yóò hùwà sí ọ gẹ́gẹ́ bi ó ṣe tọ́ sí ọ, nítorí ó ti kẹ́gàn ẹ̀jẹ́ nípa dídà májẹ̀mú. 60 Síbẹ̀ èmi yóò rántí májẹ̀mú tí mo bá ọ ṣe nígbà èwe rẹ, èmi yóò sì bá ọ dá májẹ̀mú láéláé. 61 Nígbà náà ni ìwọ yóò rántí àwọn ọ̀nà rẹ ojú yóò sì tì ọ́ nígbà tí mo bá gba àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ obìnrin padà. Fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin, ṣùgbọ́n kì í ṣe lórí májẹ̀mú tí mo bá ọ dá. 62 Èmi yóò gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì mọ pé èmi ni Olúwa. 63 Nígbà tí mo bá sì ti ṣe ètùtù fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tan, Èmi yóò sì rántí, ojú yóò tì ọ́, ìwọ kò sì ní le ya ẹnu rẹ mọ́ nítorí ìtìjú rẹ, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
+ 16:3 El 16.45.