31
Òpépé igi Sedari ni Lebanoni
1 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀:
“ ‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá?
3 Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni
Lebanoni ní ìgbà kan rí,
pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà;
tí ó ga sókè,
òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
4 Omi mú un dàgbàsókè:
orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè;
àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká,
ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
5 Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío
ju gbogbo igi orí pápá lọ;
ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn,
wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
6 Ẹyẹ ojú ọ̀run
kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀
gbogbo ẹranko igbó
ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá
ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀.
7 Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́,
pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀,
nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀
sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.
8 Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run
kò lè è bò ó mọ́lẹ̀;
tàbí kí àwọn igi junifa
ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀,
tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀,
kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run
tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.
9 Mo mú kí ó ní ẹwà
pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọ́pọ̀
tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni
tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.
10 “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga,
11 mo fi lé alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan,
12 àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárín àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìji rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀.
13 Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó ṣubú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko igbó wà ní àárín ẹ̀ka rẹ̀.
14 Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárín àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.
15 “ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jíjìn náà, mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lebanoni ní aṣọ, gbogbo igi igbó gbẹ dànù.
16 Mo mú kí orílẹ̀-èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìsàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Edeni, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lebanoni, gbogbo igi tí ó ní omi dáradára ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀.
17 Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ òjìji rẹ̀, àwọn àjèjì rẹ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa.
18 “ ‘Èwo lára igi Edeni ní a lè fiwé ọ ní dídán àti ọláńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Edeni lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárín àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.
“ ‘Èyí yìí ní Farao àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”