5
Lẹ́tà Tatenai sí Dariusi
1 Nígbà náà wòlíì Hagai àti wòlíì Sekariah, láti ìran Iddo, sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ará Júù ní Juda àti Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọ́run Israẹli tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bẹ lára wọn.
2 Nígbà náà Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti Jeṣua ọmọ Josadaki gbáradì fún iṣẹ́ àti tún ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu kọ́. Àwọn wòlíì Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú wọn, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
3 Ní àkókò náà Tatenai, baálẹ̀ ti agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹgbẹgbẹ́ wọn lọ sí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì béèrè pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ àti láti tún odi yìí mọ?”
4 Wọ́n sì tún béèrè pé, “Kí ni orúkọ àwọn ọkùnrin tí ó ń kọ́ ilé yìí?”
5 Ṣùgbọ́n ojú Ọlọ́run wọn wà lára àwọn àgbàgbà Júù, wọn kò sì dá wọn dúró títí ìròyìn yóò fi dè ọ̀dọ̀ Dariusi kí wọ́n sì gba èsì tí àkọsílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.
6 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Tatenai, olórí agbègbè Eufurate àti Ṣetar-bosnai àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn. Àwọn olóyè ti agbègbè Eufurate, fi ránṣẹ́ sí ọba Dariusi.
7 Ìròyìn tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i kà báyìí pé,
Sí ọba Dariusi,
Àlàáfíà fún un yín.
8 Kí ọba kí ó mọ̀ pé a lọ sí ẹ̀kún Juda, sí tẹmpili Ọlọ́run tí ó tóbi. Àwọn ènìyàn náà ń kọ́ ọ pẹ̀lú àwọn òkúta ńlá ńlá àti pẹ̀lú fífi àwọn igi sí ara ògiri. Wọ́n ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú àìsimi, ó sì ń ní ìtẹ̀síwájú kíákíá lábẹ́ ìṣàkóso wọn.
9 A bi àwọn àgbàgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé Olúwa yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?”
10 A sì tún béèrè orúkọ wọn pẹ̀lú, kí a lè kọ àwọn orúkọ àwọn olórí wọn sílẹ̀ kí ẹ ba à le mọ ọ́n.
11 Èyí ni ìdáhùn tí wọ́n fún wa:
“Àwa ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, àwa sì ń tún tẹmpili ilé Olúwa tí a ti kọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn kọ́, èyí tí ọba olókìkí kan ní Israẹli kọ́, tí ó sì parí i rẹ̀.
12 Ṣùgbọ́n nítorí tí àwọn baba wa mú Ọlọ́run ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadnessari ti Kaldea, ọba Babeli lọ́wọ́, ẹni tí ó run tẹmpili Olúwa yìí tí ó sì kó àwọn ènìyàn náà padà sí Babeli.
13 “Ṣùgbọ́n ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba Kirusi ọba Babeli, ọba Kirusi pàṣẹ pé kí a tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́.
14 Òun tilẹ̀ kò jáde láti inú tẹmpili ní Babeli fàdákà àti ohun èlò wúrà ilé Ọlọ́run, èyí tí Nebukadnessari kó láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu wá sí inú tẹmpili ní Babeli. Ọba Kirusi kó wọn fún ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣeṣbassari, ẹni tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí i baálẹ̀,
15 ó sì sọ fún un pé, ‘Kó àwọn ohun èlò yìí kí o lọ, kí o sì kó wọn sí inú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ipò o rẹ̀.’
16 “Nígbà náà ni Ṣeṣbassari náà wá, ó sí fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run tí ó wá ní Jerusalẹmu lélẹ̀, láti ìgbà náà àní títí di ìsinsin yìí ni o ti n bẹ ní kíkọ́ ṣùgbọ́n, kò sí tí ì parí tán.”
17 Nísinsin yìí tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, ẹ jẹ́ kí a ṣe ìwádìí nínú ìwé ìrántí ní ilé ìṣúra ọba ní Babeli láti rí bí ọba Kirusi fi àṣẹ lélẹ̀ lóòótọ́ láti tún ilé Ọlọ́run yìí kọ́ ní Jerusalẹmu. Nígbà náà jẹ́ kí ọba kó fi ìpinnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí ránṣẹ́ sí wa.