4
Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan Israẹli
1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli,
nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn
kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà.
“Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́,
Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà,
2 àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn
olè jíjà àti panṣágà.
Wọ́n rú gbogbo òfin,
ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
3 Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀,
gbogbo olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù.
Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run
àti ẹja inú omi ló ń kú.
4 “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,
kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì
nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí
àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà.
5 Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru
àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín.
Èmi ó pa ìyá rẹ run,
6 àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀.
“Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀.
Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi;
nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀,
Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
7 Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi.
Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
8 wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi,
wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
9 Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí.
Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn.
Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
10 “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;
wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,
nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa sílẹ̀,
wọ́n sì ti fi ara wọn
11 fún àgbèrè;
wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́,
àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù.
12 Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi
ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn.
Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà
wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
13 Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá,
wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré,
lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari
àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára.
Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè
àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.
14 “Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín
ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè
tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín,
nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè
nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́.
Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!
15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli,
ìdájọ́ yìí wà fún un yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi.
“Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali.
Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni
ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’
16 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí
bí alágídí ọmọ màlúù.
Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn
bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
17 Efraimu ti darapọ̀ mọ́
òrìṣà, ẹ fi sílẹ̀!
18 Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán,
wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè.
Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.
19 Ìjì ni yóò gbá wọn lọ.
Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.