4
Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje
yóò dì mọ́ ọkùnrin kan
yóò sì wí pé, “Àwa ó máa jẹ oúnjẹ ara wa
a ó sì pèsè aṣọ ara wa;
sá à jẹ́ kí a máa fi orúkọ rẹ̀ pè wá.
Mú ẹ̀gàn wa kúrò!”
Ẹ̀ka Olúwa náà
+Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli. Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu. Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná. Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sórí òkè Sioni àti sórí i gbogbo àwọn tí ó péjọpọ̀ síbẹ̀, kurukuru èéfín ní ọ̀sán àti ìtànṣán ọ̀wọ́-iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà. Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.
+ 4:2 Jr 23.5; 33.15; Sk 3.8; 6.12.