46
Àwọn Ọlọ́run Babeli
Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;
àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù.
Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di
àjàgà sí wọn lọ́rùn,
ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;
wọn kò lè gba ẹrù náà,
àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.
 
“Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu,
gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli,
ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún,
tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.
Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín,
Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró.
Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ;
Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.
 
“Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba?
Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi
tí àwa yóò jọ fi ara wé ara?
Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn
wọ́n sì wọn fàdákà lórí òsùwọ̀n;
wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,
wọn sì tẹríba láti sìn ín.
Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n,
wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí.
Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà.
Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn;
òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.
 
“Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,
fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.
Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́;
Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn;
Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.
10 Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,
láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.
Mo wí pé, Ète mi yóò dúró,
àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
11 Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;
láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.
Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ;
èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.
12 Gbọ́ tèmi, ẹ̀yin alágídí ọkàn,
ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.
13 Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí,
kò tilẹ̀ jìnnà rárá;
àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró.
Èmi yóò fún Sioni ní ìgbàlà
ògo mi fún Israẹli.