6
Ìpè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Isaiah
Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. +Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé,
“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
+Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.
Mo kígbe pé, “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.
Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ. Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”
Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”
Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”
+Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé,
“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,
mú kí etí wọn kí ó wúwo,
kí o sì dìwọ́n ní ojú.
Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,
kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,
kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,
kí wọn kí ó má ba yípadà
kí a má ba mú wọn ní ara dá.”
11 Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?”
Òun sì dáhùn pé:
“Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro,
láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́,
títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn,
títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá.
12 Títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré
tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá.
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà,
yóò sì tún pàpà padà di rírun.
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù,
ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”
+ 6:3 If 4.8. + 6:4 If 15.8. + 6:9 Mt 13.14-15; Mk 4.12; Lk 8.10; Jh 12.39-41; Ap 28.26-27.