Ìwé Johanu Kìn-ín-ní
1
Ọ̀rọ̀ Ìyè
+Èyí tí ó wà láti àtètèkọ́ṣe, tí àwa ti gbọ́, tí àwa ti fi ojú wa rí, tí àwa sì ti tẹjúmọ́, tí ọwọ́ wa sì ti dì mú; èyí tí a kéde; ní ti ọ̀rọ̀ ìyè; iyè náà sì ti farahàn, àwa sì ti rí i, àwa sì ń jẹ́rìí, àwa sì ń sọ ti ìyè àìnípẹ̀kun náà fún yín, tí ó ti ń bẹ lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa. Àwa ń sọ fún yín, èyí tí àwa ti rí, tí àwa sì ti gbọ́, kí ẹ̀yin pẹ̀lú kí ó lè ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú wa. Nítòótọ́ ìdàpọ̀ wa sì ń bẹ pẹ̀lú Baba àti pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. +Àwa sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ayọ̀ yín kí ó lè di kíkún.
Rírìn nínú ìmọ́lẹ̀
+Èyí sì ni iṣẹ́ tí àwa ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, tí àwa sì ń jẹ́ fún yín pé, ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọ́run; ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì òkùnkùn rárá. +Bí àwa bá wí pé àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí àwa sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa ń ṣèké, àwa kò sì gbé nínú òtítọ́. +Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara wa, àti pé ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi, Ọmọ rẹ̀, wẹ̀ wá nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo.
Bí àwa bá wí pé àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kan kò sì ṣí nínú wa. Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtítọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo. 10  +Bí àwa bá wí pé àwa kò dẹ́ṣẹ̀, àwa mú un ní èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ṣí nínú wa.
+ 1:1 Lk 24.39; Jh 1.1; 4.14; 15.27; 20.20,25; Ap 4.20; 1Jh 2.13. + 1:4 Jh 15.11; 2Jh 12. + 1:5 1Jh 3.11. + 1:6 Jh 3.2; 1Jh 2.4,11. + 1:7 If 1.5. + 1:10 1Jh 5.10.