19
Ìdáhùn Jobu fún Bilidadi
Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé:
“Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí,
tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí?
Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí;
ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.
Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́,
ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́,
tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú,
ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.
 
“Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;
mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.
Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá,
Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
Ó ti bọ́ ògo mi,
ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
10 Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,
ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11 Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi,
ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
12 Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi,
wọ́n sì mọ odi yí mi ká,
wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.
 
13 “Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré,
àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.
14 Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn,
àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi.
15 Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì;
èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.
16 Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn;
mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.
17 Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi
ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
18 Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín,
mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi,
àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
20 Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi,
mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.
 
21 “Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,
ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.
22 Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí
Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?
 
23 “Háà! Ìbá ṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi nísinsin yìí,
ìbá ṣe pé a le kọ ọ sínú ìwé!
24 Kí a fi kálámù irin àti ti òjé kọ
wọ́n sínú àpáta fún láéláé.
25 Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáǹdè mi ń bẹ láààyè
àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;
26 àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run,
síbẹ̀ láìsí ẹran-ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,
27 ẹni tí èmi ó rí fún ara mi,
tí ojú mi ó sì wo, kì sì í ṣe ti ẹlòmíràn;
ọkàn mi sì dákú ní inú mi.
 
28 “Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa ó ti lépa rẹ̀ tó!
Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a sá à rí ní ọwọ́ rẹ̀,’
29 kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù,
nítorí ìbínú ní í mú ìjìyà wá nípa idà,
kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”