7
Jobu ha ni ìrètí bí?
“Ṣé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀?
Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe?
Bí ọmọ ọ̀dọ̀ tí máa ń kánjú bojú wo òjìji,
àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù,
òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.
Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, èmi wí pé, ‘Nígbà wo ni èmi ó dìde?’
Tí òru yóò sì kọjá, ó sì tó fún mi láti yí síyìn-ín yí sọ́hùn-ún, títí yóò fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.
Kòkòrò àti ògúlùtu erùpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ,
awọ ara mi bù, o sì di bíbàjẹ́.
 
“Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ,
o sì di lílò ní àìní ìrètí.
Háà! Rántí pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi;
ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.
Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́;
ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.
Bí ìkùùkuu tí i túká, tí í sì fò lọ,
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.
10 Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,
bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.
 
11 “Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́,
èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi,
èmi yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.
12 Èmi a máa ṣe Òkun tàbí ẹ̀mí búburú,
tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?
13 Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára,
ìtẹ́ mi yóò mú ara mi fúyẹ́ pẹ̀lú.
14 Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da yọ mi lénu bò mi,
ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rùbà mí.
15 Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti fún pa
àti ikú ju kí ń wà láààyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.
16 O sú mi, èmi kò le wà títí:
jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.
 
17  +“Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀?
Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọkàn rẹ lé e?
18 Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀,
ti ìwọ o sì máa dán an wò nígbàkígbà!
19 Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ,
tí ìwọ o fi mí sílẹ̀ jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi lè dá itọ́ mi mì.
20 Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó ṣe sí ọ.
Ìwọ Olùsójú ènìyàn?
Èéṣe tí ìwọ fi fi mí ṣe àmì itasi níwájú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni èmi sì di ẹrẹ̀ wíwo fún ọ?
21 Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn,
kí ìwọ kí ó sì mú àìṣedéédéé mi kúrò?
Ǹjẹ́ nísinsin yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀,
ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní òwúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”
+ 7:17 Sm 8.4.