2
Israẹli kọ Ọlọ́run sílẹ̀
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá wí pé:
2 “Lọ kí o sì kéde sí etí Jerusalẹmu pé:
“Báyìí ni Olúwa wí,
“ ‘Èmi rántí ìṣeun ìgbà èwe rẹ,
ìfẹ́ ìgbéyàwó rẹ
àti nígbà tí ìwọ tẹ̀lé mi nínú ijù,
nínú ìyàngbẹ ilẹ̀.
3 Israẹli jẹ́ mímọ́ sí Olúwa,
àkọ́kọ́ èso ìkórè rẹ̀,
gbogbo ẹnikẹ́ni tí ó jẹ run ni a ó dá lẹ́bi,
ibi yóò sì wá sí orí wọn,’ ”
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
4 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu
àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli.
5 Báyìí ni Olúwa wí:
“Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi,
tí wọ́n fi jìnnà sí mi?
Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,
àwọn fúnra wọn sì di asán.
6 Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà,
tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
tí ó mú wa la aginjù já,
tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò,
ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri,
ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’
7 Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá
láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,
ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
8 Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé,
‘Níbo ni Olúwa wà?’
Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí,
àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi.
Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali,
wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.
9 “Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,”
ni Olúwa wí.
“Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ.
10 Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,
ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi;
kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?
11 Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà?
(Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.)
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀
Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
12 Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”
ni Olúwa wí.
13 “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì,
wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀,
Èmi orísun omi ìyè,
wọ́n sì ti ṣe àmù,
àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.
14 Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ ẹrú nípa ìbí?
Kí ló ha a dé tí ó fi di ìkógun?
15 Àwọn kìnnìún ké ramúramù;
wọ́n sì ń bú mọ́ wọn.
Wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò;
ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì ti di ìkọ̀sílẹ̀.
16 Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi
wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
17 Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí ara yín
nípa kíkọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀
nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
18 Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti
láti lọ mu omi ní Ṣihori?
Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria
láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?
19 Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín
ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí
mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti
ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ
nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀,
ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”
ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
20 “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù,
ìwọ sì já ìdè rẹ;
ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’
Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni
àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀
ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.
21 Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àjàrà ọ̀tọ̀,
gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá.
Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi
di àjàrà búburú àti aláìmọ́?
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà
tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ
síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,”
ni Olúwa Olódùmarè wí.
23 “Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́,
Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’?
Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;
wo ohun tí o ṣe.
Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ
tí ń sá síyìn-ín sọ́hùn-ún.
24 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù
tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ,
ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀?
Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara,
nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.
25 Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà,
àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ.
Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni!
Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì,
àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’
26 “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u,
bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli—
àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn,
àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.
27 Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’
àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’
wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi,
wọn kò kọ ojú sí mi
síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro,
wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’
28 Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí ẹ ṣe fúnra yín ha a wà?
Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì gbà yín
nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro!
Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀,
gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda.
29 “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?
Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”
ni Olúwa wí.
30 “Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín,
wọn kò sì gba ìbáwí.
Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run,
gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.
31 “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ Olúwa:
“Mo ha ti di aginjù sí Israẹli
tàbí mo jẹ ilẹ̀ olókùnkùn biribiri?
Èéṣe tí àwọn ènìyàn mi ṣe wí pé, ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri;
àwa kì yóò tọ̀ ọ́ wá mọ́?’
32 Wúńdíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀,
tàbí ìyàwó ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀?
Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi
ní ọjọ́ àìníye.
33 Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́!
Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ.
34 Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá
ẹ̀jẹ̀ àwọn tálákà aláìṣẹ̀,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́ níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé.
Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí
35 ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀;
kò sì bínú sí mi.’
Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹ
nítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’
36 Èéṣe tí ìwọ fi ń lọ káàkiri
láti yí ọ̀nà rẹ padà?
Ejibiti yóò dójútì ọ́
gẹ́gẹ́ bí i ti Asiria.
37 Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀
pẹ̀lú kíkáwọ́ rẹ lé orí rẹ,
nítorí pé Olúwa ti kọ̀ àwọn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé sílẹ̀,
kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn.