22
Ìdájọ́ fún àwọn ọba búburú
1 Báyìí ni Olúwa wí, “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ààfin ọba Juda, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀:
2 ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ìwọ ọba Juda, tí ó jókòó ní ìtẹ́ Dafidi, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí.
3 Báyìí ni Olúwa wí: Ṣé ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí ó sì yẹ, kí o sì gba ẹni tí a fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú kúrò lọ́wọ́ aninilára. Kí ó má ṣe fi agbára àti ìkà lé àlejò, aláìní baba, tàbí opó, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ níbí yìí.
4 Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba inú ààfin láti ẹnu-ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn.
5 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, mo búra fúnra mi pé ààfin yìí yóò di ìparun ni Olúwa wí.’ ”
6 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa ààfin ọba Juda,
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gileadi sí mi,
gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lebanoni,
dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀,
àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.
7 Èmi ó ya àwọn apanirun sọ́tọ̀ fún ọ,
olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀,
wọn yóò sì gé àṣàyàn igi kedari rẹ lulẹ̀,
wọn ó sì kó wọn jù sínú iná.
8 “Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò rékọjá lẹ́bàá ìlú yìí wọn yóò sì máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Èéṣe tí Olúwa ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?’
9 Ìdáhùn wọn yóò sì jẹ́: ‘Nítorí tí wọ́n ti kọ májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọn ti ń fi orí balẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn, wọ́n sì sìn wọ́n.’ ”
10 Nítorí náà má ṣe sọkún nítorí ọba tí ó ti kú tàbí ṣọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ sọkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùú
nítorí kì yóò padà wá mọ́
tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i.
11 Nítorí báyìí ni Olúwa wí, nípa Ṣallumu ọmọ Josiah ọba Juda tí ó jẹ ọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn-ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́.
12 Yóò kú ni ibi tí a mú u ní ìgbèkùn lọ, kì yóò sì rí ilẹ̀ yìí mọ́.”
13 “Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìṣòdodo,
àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́
tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán
láìsan owó iṣẹ́ wọn fún wọn.
14 Ó wí pé, ‘Èmi ó kọ́ ààfin ńlá fún ara mi
àwọn yàrá òkè tí ó fẹ̀,
ojú fèrèsé rẹ̀ yóò tóbi.’
A ó sì fi igi kedari bò ó,
a ó fi ohun aláwọ̀ pupa ṣe é ní ọ̀ṣọ́.
15 “Ìwọ ó ha jẹ ọba
kí ìwọ kí ó lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari?
Baba rẹ kò ha ní ohun jíjẹ àti mímu?
Ó ṣe ohun tí ó tọ́ àti òdodo,
nítorí náà ó dára fún un.
16 Ó gbèjà òtòṣì àti aláìní,
ohun gbogbo sì dára fún un.
Bí a ti mọ̀ mí kọ́ ni èyí?”
ni Olúwa wí.
17 “Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ
wà lára èrè àìṣòótọ́
láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀
ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”
18 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, nípa Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:
“Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:
wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’
Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un:
wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe ọlọ́lá!’
19 A ó sin òkú rẹ̀ bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
tí a wọ́ sọnù láti ẹnu ibodè
Jerusalẹmu.”
20 “Gòkè lọ sí Lebanoni, kígbe síta,
kí a sì gbọ́ ohùn rẹ ní Baṣani,
kí o kígbe sókè láti Abarimu,
nítorí a ti ṣẹ́ gbogbo olùfẹ́ rẹ túútúú.
21 Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu,
ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’
Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ,
ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.
22 Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ,
gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbèkùn,
nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́
nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.
23 Ìwọ tí ń gbé ‘Lebanoni,’
tí ó tẹ́ ìtẹ́ sí orí igi kedari,
ìwọ yóò ti kérora pẹ́ tó, nígbà tí ìrora bá dé bá ọ,
ìrora bí i ti obìnrin tí ń rọbí!
24 “Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.
25 Èmi ó sì fà ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí rẹ, àwọn tí ìwọ bẹ̀rù, àní lé ọwọ́ Nebukadnessari, ọba Babeli àti ọwọ́ àwọn ará Babeli.
26 Èmi ó fi ìwọ àti ìyá tí ó bí ọ sọ̀kò sí ilẹ̀ mìíràn, níbi tí a kò bí ẹnikẹ́ni nínú yín sí. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì yóò kú sí.
27 Ẹ̀yin kì yóò padà sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin fẹ́ mọ́ láéláé.”
28 Ǹjẹ́ Jehoiakini ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo,
ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́?
Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókè
sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.
29 Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀,
gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa!
30 Báyìí ni Olúwa wí:
“Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,
ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀;
nítorí ọ̀kan nínú irú-ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere,
èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi
tàbí jẹ ọba ní Juda mọ́.”