16
Ìpín fún ẹ̀yà Efraimu àti Manase
Ìpín ti àwọn ọmọ Josẹfu láti Jordani lẹ́bàá Jeriko, ní omi Jeriko ní ìhà ìlà-oòrùn, àní aginjù, tí ó gòkè láti Jeriko lọ dé ilẹ̀ òkè Beteli. Ó sì tẹ̀síwájú láti Beteli (tí í ṣe Lusi) kọjá lọ sí agbègbè àwọn ará Arki ní Atarotu, Ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn agbègbè àwọn ará Jefileti, títí dé ilẹ̀ ìsàlẹ̀ Beti-Horoni, àní dé Geseri, ó sì parí sí etí Òkun.
 
Báyìí ni Manase àti Efraimu, àwọn ọmọ Josẹfu, gba ilẹ̀ ìní wọn.
 
 
Èyí ni ilẹ̀ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé.
 
Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Addari ní ìlà-oòrùn lọ sí òkè Beti-Horoni. Ó sì lọ títí dé Òkun. Láti Mikmeta ní ìhà àríwá, ó sì yí lọ sí ìhà ìlà-oòrùn lọ sí Taanati-Ṣilo, ó sì kọjá ní ẹ̀bá rẹ̀ lọ sí Janoa ní ìlà-oòrùn. Láti Janoa ó yípo lọ sí gúúsù sí Atarotu àti Naara, ó sì dé Jeriko, ó sì pín sí odò Jordani. Láti Tapua ààlà náà sì lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, ní Kana-Rafini, ó sì parí ní Òkun. Èyí ni ìní ẹ̀yà àwọn ọmọ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé.
Ó tún mú àwọn ìlú àti ìletò wọn tí ó yà sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Efraimu tí ó wà ní àárín ìní àwọn ọmọ Manase.
 
10  +Wọn kò lé àwọn ara Kenaani tí ń gbé ni Geseri kúrò, títí di òní yìí ni àwọn ará Kenaani ń gbé láàrín àwọn ènìyàn Efraimu, ṣùgbọ́n wọ́n mú wọ́n sìn.
+ 16:10 On 1.29; 2Sa 5.6.