Ìwé Wòlíì Nahumu
1
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ nípa Ninefe. Ìwé ìran Nahumu ará Elkoṣi.
 
Ìbínú Olúwa sí Ninefe
Ọlọ́run ń jẹ owú, ó sì ń gbẹ̀san,
Olúwa ń gbẹ̀san, ó sì kún fún ìbínú.
Olúwa ń gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Ìbínú rẹ̀ kò sì yí padà lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
+Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára;
Olúwa kì yóò fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà.
Ọ̀nà rẹ̀ wà nínú afẹ́fẹ́ àti nínú ìjì,
ìkùùkuu sánmọ̀ sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
Ó bá òkun wí, ó sì mú kí ó gbẹ;
Ó sìsọ gbogbo odò di gbígbẹ.
Baṣani àti Karmeli sì rọ.
Ìtànná Lebanoni sì rẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn òkè ńlá wárìrì níwájú rẹ̀,
àwọn òkè kéékèèké sì di yíyọ́,
ilẹ̀ ayé sì jóná níwájú rẹ̀,
àní ayé àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
Ta ni ó lé dúró níwájú ìbínú rẹ̀?
Ta ni ó lé faradà gbígbóná ìbínú rẹ̀?
Ìbínú rẹ̀ tú jáde bí iná;
àwọn àpáta sì fọ́ túútúú níwájú rẹ̀.
 
Rere ni Olúwa,
òun ni ààbò ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Òun sì tọ́jú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìkún omi ńlá
ní òun yóò fi ṣe ìparun láti ibẹ̀ dé òpin;
òkùnkùn yóò sì máa lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀.
 
Kí ni ẹ̀yìn ń gbìmọ̀ lòdì sí Olúwa?
Òun yóò fi òpin sí i,
ìpọ́njú kì yóò wáyé ní ìgbà kejì.
10 Wọn yóò sì lọ́lù papọ̀ bí ẹ̀gún òṣùṣú
wọn yóò sì mu àmupara nínú ọtí wáìnì wọn
a ó sì run wọn gẹ́gẹ́ bi àgékù koríko gbígbẹ.
11 Láti ọ̀dọ̀ rẹ, ìwọ Ninefe, ni ẹnìkan ti jáde wá
tí ó ń gbèrò ibi sí Olúwa
ti ó sì ń gbìmọ̀ búburú.
12 Báyìí ni Olúwa wí:
“Bí wọ́n tilẹ̀ ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọ́n sì pọ̀ níye,
ṣùgbọ́n, báyìí ní a ó ké wọn lulẹ̀,
nígbà tí òun ó bá kọjá.
Bí mo tilẹ̀ ti pọ́n ọ lójú ìwọ Juda, èmi kì yóò pọ́n ọ lójúmọ́.
13 Nísinsin yìí ni èmi yóò já àjàgà wọn kúrò ní ọrùn rẹ
èmi yóò já ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ dànù.”
 
14  Olúwa ti fi àṣẹ kan lélẹ̀ nítorí tìrẹ Ninefe:
“Ìwọ kì yóò ni irú-ọmọ láti máa jẹ́ orúkọ rẹ mọ́,
Èmi yóò pa ère fínfín àti ère dídà run
tí ó wà nínú tẹmpili àwọn ọlọ́run rẹ.
Èmi yóò wa ibojì rẹ,
nítorí ẹ̀gbin ni ìwọ.”
 
15  +Wò ó, lórí àwọn òkè,
àwọn ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìròyìn ayọ̀ wá,
ẹni tí ó ń kéde àlàáfíà.
Ìwọ Juda, pa àṣẹ rẹ tí ó ní ìrònú mọ́,
kí ó sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ.
Àwọn ènìyàn búburú kì yóò sì gbóguntì ọ́ mọ́;
wọn yóò sì parun pátápátá.
+ 1:3 Isa 10.5-34; Sf 2.12-15. + 1:15 Isa 40.9; 52.7; Ap 10.36; Ro 10.15.