23
Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ Balaamu
1 Balaamu wí fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.”
2 Balaki ṣe bí Balaamu ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
3 Nígbà náà Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá Olúwa yóò farahàn mí. Ohunkóhun tí ó bá fihàn mí, èmi yóò wí fún ọ.” Nígbà náà ó sì lọ sí ibi gíga.
4 Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Balaamu sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ.”
5 Olúwa sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Balaamu ó wí pé, “Padà sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí fún un.”
6 Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu.
7 Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé,
“Balaki mú mi láti Aramu wá,
ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá
Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi;
wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’
8 Báwo ní èmi ó ṣe fi bú
àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú?
Báwo ni èmi ó ṣe bá wọn wí
àwọn tí Olúwa kò bá wí?
9 Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn,
láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n.
Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀
wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Ta ni ó lè ka eruku Jakọbu
tàbí ka ìdámẹ́rin Israẹli?
Jẹ́ kí èmi kú ikú olódodo,
kí ìgbẹ̀yìn mi kí ó dà bí tirẹ̀!”
11 Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”
12 Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”
Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ èkejì Balaamu
13 Nígbà náà Balaki sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.”
14 Ó sì lọ sí pápá Sofimu ní orí òkè Pisga, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
15 Balaamu ṣo fún Balaki pé, “Dúró níbí ti ẹbọ sísun rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ̀.”
16 Olúwa pàdé Balaamu ó sì fi ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jíṣẹ́ fún un.”
17 Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?”
18 Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ,
“Dìde, Balaki;
kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori.
19 Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́,
tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà.
Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é?
Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?
20 Èmi gba àṣẹ láti bùkún;
Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.
21 “Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jakọbu,
kò sì rí búburú kankan nínú Israẹli.
Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn.
Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.
22 Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá,
wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.
23 Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jakọbu,
tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Israẹli.
Nísinsin yìí a ó sọ nípa ti Jakọbu
àti Israẹli, ‘Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe!’
24 Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún;
wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún
òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ
títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.”
25 Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!”
26 Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí Olúwa bá sọ, òun ni èmi yóò ṣe?”
Ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ẹ̀kẹta Balaamu
27 Nígbà náà Balaki sọ fún Balaamu pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.”
28 Balaki gbé Balaamu wá sí orí òkè Peori, tí ó kọjú sí aginjù.
29 Balaamu sì wí fún Balaki pé, “Mọ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.”
30 Balaki sì ṣe bí Balaamu ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.