12
Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀,
ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.
 
Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa
ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.
 
A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú
ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.
 
Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀
ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.
 
Èrò àwọn olódodo tọ́,
ṣùgbọ́n ìgbìmọ̀ ènìyàn búburú jẹ́ ẹ̀tàn.
 
Ọ̀rọ̀ ènìyàn búburú lúgọ de ẹ̀jẹ̀
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ àwọn olódodo gbà wọ́n là.
 
A ṣí àwọn ènìyàn búburú ní ìdí, wọn kò sì sí mọ́;
ṣùgbọ́n ilé olódodo dúró ṣinṣin.
 
A ń yín ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ọgbọ́n rẹ̀
ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ọlọ́pọlọ wúruwùru ni a kẹ́gàn.
 
Ó sàn kí a má jẹ́ ènìyàn pàtàkì kí a sì ní ìránṣẹ́
ju kí a díbọ́n pé a jẹ́ ẹni pàtàkì láìní oúnjẹ.
 
10 Olódodo ènìyàn ń ṣe aájò ohun tí àwọn ohun ọ̀sìn rẹ̀ nílò,
ṣùgbọ́n ìyọ́nú àwọn ènìyàn búburú, ìkà ni.
 
11 Ẹni tí ó bá dá oko yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ,
ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa òjìji lásán làsàn kò gbọ́n.
 
12 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ìkógun àwọn ènìyàn ìkà
ṣùgbọ́n gbòǹgbò olódodo ń gbilẹ̀.
 
13 A mú ènìyàn búburú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀
ṣùgbọ́n olódodo bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdààmú.
 
14 Láti inú èso rẹ̀, ènìyàn kún fún onírúurú ohun rere
bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ti ń pín in lérè dájúdájú.
 
15 Ọ̀nà aláìgbọ́n dára lójú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa gba ìmọ̀ràn.
 
16 Aláìgbọ́n ènìyàn fi ìbínú un rẹ̀ hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀,
ṣùgbọ́n olóye ènìyàn fojú fo ìyànjẹ.
 
17 Ẹni tí ó jẹ́ ajẹ́rìí òtítọ́ jẹ́rìí ohun tí ojú rẹ̀ rí
ṣùgbọ́n ajẹ́rìí èké máa ń parọ́.
 
18 Ọ̀rọ̀ tí a kò rò jinlẹ̀ máa ń gún ni bí ọ̀kọ̀
ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n ń mú ìwòsàn wá.
 
19 Ètè tí ń ṣọ òtítọ́ yóò wà láéláé
ṣùgbọ́n ahọ́n tí ń parọ́ kì í tọ́jọ́.
 
20 Ẹ̀tàn wà nínú ọkàn àwọn tí ń pète búburú
ṣùgbọ́n ayọ̀ wà fún àwọn tí ń mú kí àlàáfíà gbilẹ̀.
 
21 Ibi kì í ṣubú lu olódodo rárá
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú gba ìpín ìyọnu tiwọn.
 
22  Olúwa kórìíra ètè tí ń parọ́
ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn olóòtítọ́.
 
23 Ènìyàn olóye fi ìmọ̀ rẹ̀ pamọ́ sínú ara rẹ̀
ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn búburú ń gbé ìwà òmùgọ̀ jáde.
 
24 Ọwọ́ àìṣọ̀lẹ yóò jẹ ọba
ṣùgbọ́n ọ̀lẹ ṣíṣe a máa yọrí sí ẹrú ṣíṣe.
 
25 Ìbànújẹ́ ní ọkàn ènìyàn ní dorí rẹ̀ kodò
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere a máa mú kó yọ̀.
 
26 Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.
 
27 Ọ̀lẹ ènìyàn kò sun ẹran tí ó pa lóko ọdẹ
ṣùgbọ́n ẹni tí kì í ṣe ọ̀lẹ máa ń díwọ̀n ohun ìní rẹ̀.
 
28 Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà
ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.