21
Ọkàn ọba ń bẹ lọ́wọ́ Olúwa;
a máa darí rẹ̀ lọ ibi tí ó fẹ́ bí ipa omi.
 
Gbogbo ọ̀nà ènìyàn dàbí i pé ó dára lójú rẹ̀,
ṣùgbọ́n, Olúwa ló ń díwọ̀n ọkàn.
 
Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà
ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ.
 
Ojú tí ó gbéga àti ọkàn ìgbéraga,
ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn búburú, ẹ̀ṣẹ̀ ni!
 
Ètè àwọn olóye jásí èrè
bí ìkánjú ṣe máa ń fa òsì kíákíá.
 
Ìṣúra tí a kójọ nípasẹ̀ ahọ́n tí ń parọ́
jẹ́ ìrì lásán àti ìkẹ́kùn ikú.
 
Ìwà ipá àwọn ènìyàn búburú yóò wọ́ wọn lọ,
nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́.
 
Ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ kún fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀
ṣùgbọ́n iṣẹ́ onínú funfun jẹ́ títọ́.
 
Ó sàn láti máa gbé ní kọ̀rọ̀ orí òrùlé
ju láti ṣe àjọpín ilé pẹ̀lú aya oníjà.
 
10 Ènìyàn búburú ń fẹ́ ibi
aládùúgbò rẹ̀ kì í rí àánú kankan gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.
 
11 Nígbà tí a bá ń fìyà jẹ ẹlẹ́gàn,
òpè a máa kọ́gbọ́n,
nígbà tí a bá sì kọ́ ọlọ́gbọ́n yóò ní ìmọ̀.
 
12 Olódodo ṣàkíyèsí ilé ènìyàn búburú
ó sì mú ènìyàn búburú wá sí ìparun.
Ìṣúra ẹni tí o gbọ́n
13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ti di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ́njú,
òun tìkára rẹ̀ yóò ké pẹ̀lú;
ṣùgbọ́n a kì yóò gbọ́.
 
14 Ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀, mú ìbínú kúrò:
àti owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti ibi ìkọ̀kọ̀ wá,
dẹ́kun ìbínú líle.
 
15 Ayọ̀ ni fún olódodo láti ṣe ìdájọ́:
ṣùgbọ́n ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
 
16 Ẹni tí ó bá yà kúrò ní ọ̀nà òye,
yóò máa gbé inú ìjọ àwọn òkú.
 
17 Ẹni tí ó bá fẹ́ afẹ́, yóò di tálákà:
ẹni tí ó fẹ́ ọtí wáìnì pẹ̀lú òróró kò le lọ́rọ̀.
 
18 Ènìyàn búburú ni yóò ṣe owó ìràpadà fún olódodo,
àti olùrékọjá fún ẹni dídúró ṣinṣin.
 
19 Ó sàn láti jókòó ní aginjù ju pẹ̀lú
oníjà obìnrin àti òṣónú lọ.
 
20 Ìṣúra iyebíye àti òróró wà ní ibùgbé ọlọ́gbọ́n;
ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn n bà á jẹ́.
 
21 Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè,
òdodo, àti ọlá.
 
22 Ọlọ́gbọ́n gòkè odi ìlú àwọn alágbára,
ó sì bi ibi gíga agbára ìgbẹ́kẹ̀lé wọn ṣubú.
 
23 Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ẹnu àti ahọ́n rẹ̀ mọ́,
ó pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìyọnu.
 
24 Agbéraga àti alágídí ènìyàn ń gan orúkọ ara rẹ̀ nítorí ó ń hùwà nínú ìwà ìgbéraga rẹ̀,
àti nínú ìbínú púpọ̀púpọ̀.
 
25 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé, àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò parun láé;
nítorí tí ọwọ́ rẹ̀ kọ iṣẹ́ ṣíṣe.
26 Ó ń fi ìlara ṣe ojúkòkòrò ní gbogbo ọjọ́:
ṣùgbọ́n olódodo a máa fi fún ni kì í sì í dáwọ́ dúró.
 
27 Ẹbọ ènìyàn búburú, ìríra ni:
mélòó mélòó ni nígbà tí ó mú un wá pẹ̀lú èrò ìwà ibi?
 
28 Ẹlẹ́rìí èké yóò ṣègbé:
ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹni tí ó gbọ́, yóò dúró.
 
29 Ènìyàn búburú mú ojú ara rẹ̀ le:
ṣùgbọ́n ẹni ìdúró ṣinṣin ni ó ń mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́.
 
30 Kò sí ọgbọ́n, kò sí ìmòye,
tàbí ìmọ̀ràn tí ó le mókè níwájú Olúwa.
 
31 A ń múra ẹṣin sílẹ̀ de ọjọ́ ogun:
ṣùgbọ́n ìṣẹ́gun jẹ́ ti Olúwa.