Àwọn ọ̀rọ̀ ọba Lemueli
31
Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ,
“Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi!
Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.
Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,
okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.
 
“Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli,
kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì,
kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle,
kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí,
kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n.
Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé
wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora.
Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn
kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.
 
“Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnra wọn
fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun.
Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè
jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”
Ìkádìí: Aya oníwà rere
10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere?
Ó níye lórí ju iyùn lọ.
11 Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀
kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.
12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi
ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
13 Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀
Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.
14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;
ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn.
15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;
ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀
àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.
16 Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;
nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀.
17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára
apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́.
18 Ó rí i pé òwò òun pé
fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru.
19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú
ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú.
20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà
ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀
nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;
ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀.
23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú
níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú.
24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n
ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò.
25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ
ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n
ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀
kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́.
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún
ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un.
29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá
ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ.”
30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán
nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn.
31 Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i
kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.