Saamu 11
Fún adarí orin. Ti Dafidi.
Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.
Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé,
“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.
Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;
wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn
láti tafà níbi òjìji
sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́
kí ni olódodo yóò ṣe?”
 
Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.
Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;
ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
Olúwa ń yẹ olódodo wò,
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá
ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.
Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò
ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;
àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.
 
Nítorí, olódodo ní Olúwa,
o fẹ́ràn òdodo;
ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.