Saamu 124
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. 
 
1 “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,”  
kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;   
2 ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa,  
nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,   
3 nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè  
nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,   
4 nígbà náà ni omi  
wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,   
5 nígbà náà ni agbéraga  
omi ìbá borí ọkàn wa.   
   
 
6 Olùbùkún ni Olúwa, tí kò fi wá fún wọ́n  
bí ohun ọdẹ fún eyín wọn.   
7 Ọkàn wa yọ bí ẹyẹ jáde kúrò nínú okùn apẹyẹ;  
okùn já àwa sì yọ.   
8 Ìrànlọ́wọ́ wa ń bẹ ní orúkọ Olúwa,  
tí ó dá ọ̀run òun ayé.