Saamu 126
Orin fún ìgòkè. 
 
1 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,  
àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.   
2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,  
àti ahọ́n wa kọ orin;  
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,  
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.   
3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;  
nítorí náà àwa ń yọ̀.   
   
 
4 Olúwa mú ìkólọ wa padà,  
bí ìṣàn omi ní gúúsù.   
5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn  
yóò fi ayọ̀ ka.   
6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,  
tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,  
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,  
yóò sì ru ìtí rẹ̀.