Saamu 13
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?
Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,
àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?
Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?
 
Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.
Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú.
Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”
àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.
 
Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;
ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,
nítorí ó dára sí mi.