Saamu 137
Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
tí ó wà láàrín rẹ̀.
Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá;
wọn wí pé, “Ẹ kọ orin Sioni kan fún wa!”
 
Àwa ó ti ṣe kọ orin
Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
Bí èmi kò bá rántí rẹ,
jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
olórí ayọ̀ mi gbogbo.
 
Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
“Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
bí ìwọ ti rò sí wa.
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.