Saamu 149
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
 
Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.
 
Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
ayọ̀ nínú ọba wọn.
Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.
 
Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
àti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.
 
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.