Saamu 18
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé.
+Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.
 
Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;
Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.
Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
 
Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,
a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
Ìrora ikú yí mi kà,
àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
Okùn isà òkú yí mi ká,
ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
 
Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;
mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.
Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;
ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,
ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí;
wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;
àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10 Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;
ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11 Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká
kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
12 Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ
pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
13  Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá;
Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
14 Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká,
ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
15 A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn òkun hàn,
a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé
nípa ìbáwí rẹ, Olúwa,
nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
 
16 Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú;
Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
17 Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
18 Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;
ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.
19 Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;
Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
 
20  Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi.
21 Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́;
èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
22 Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;
èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
23 Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀;
mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
24  Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.
 
25 Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́,
sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
26 sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,
ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
27 O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
28 Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi
kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
29 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ;
pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
 
30 Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé,
a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa
òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31 Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?
Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?
32 Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè
ó sì mú ọ̀nà mi pé.
33 Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín;
ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
34 Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà;
apá mi lè tẹ ọrùn idẹ.
35 Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró;
àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
36 Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi,
kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
 
37 Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn
èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
38 Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde;
wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39 Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà;
ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
40 Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi
èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
41 Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n,
àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
42 Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́;
mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
43 Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;
Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
44 ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́;
àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
45 Àyà yóò pá àlejò;
wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
 
46  Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi!
Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
47 Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,
tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
48 tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.
Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ;
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
49  +Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa;
èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.
 
50 Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;
ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni àmì òróró rẹ̀,
fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.
+ Saamu 18:1 2Sa 22.2-51. + Saamu 18:49 Ro 15.9.