Saamu 39
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.
Mo wí pé, “Èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
 
Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
Ìwọ ti ṣe ayé mi
bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
ní iwájú rẹ.
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá.
Sela.
 
“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
 
“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.
 
12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi.
Nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ,
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”