Saamu 46
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. Orin. 
 
1 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa  
ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.   
2 Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,  
tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.   
3 Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì  
tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. 
Sela.
   
   
 
4 Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,  
ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.   
5 Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:  
Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.   
6 Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,  
ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.   
   
 
7 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,  
Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.   
   
 
8 Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa  
irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.   
9 O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé  
ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì  
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.   
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.  
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè,  
a ó gbé mi ga ní ayé.   
   
 
11 Olúwa àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa;  
Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.