Saamu 74
Maskili ti Asafu.
Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà.
Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.
 
Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
láàrín ènìyàn rẹ,
wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún àmì.
Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
láti gé igi igbó dídí.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́.
Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
 
A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
kò sí wòlíì kankan
ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
 
12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.
 
13 Ìwọ ni ó la òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi.
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ.
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.
 
18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.