Saamu 92
Saamu. Orin. Fún Ọjọ́ Ìsinmi.
Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́,
lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
àti lára ohun èlò orin haapu.
 
Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa?
Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!
Òpè ènìyàn kò mọ̀ ọ́n,
aṣiwèrè kò sì mọ̀ ọ́n,
nígbà tí àwọn ènìyàn búburú bá rú jáde bí i koríko
àti gbogbo àwọn olùṣe búburú gbèrú,
wọn yóò run láéláé.
 
Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.
 
Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ,
Olúwa,
nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;
gbogbo àwọn olùṣe búburú
ni a ó fọ́nká.
10 Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;
òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.
11 Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi;
ìparun sí àwọn ènìyàn búburú
tí ó dìde sí mi.
 
12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni,
13 tí a gbìn sí ilé Olúwa,
Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
kankan nínú rẹ̀.”