9
Ọlọ́run yan Israẹli
Òtítọ́ ni èmi ń sọ nínú Kristi, èmi kò ṣèké, ọkàn mi sì ń jẹ́ mi ní ẹ̀rí nínú Ẹ̀mí Mímọ́. Pé mo ní ìbìnújẹ́ púpọ̀, àti ìkáàánú ìgbà gbogbo ni ọkàn mi. +Nítorí mo fẹ́rẹ lè gbàdúrà pé kí èmi tìkára mi kúrò lọ́dọ̀ Kristi nítorí àwọn ará mi, àwọn ìbátan mi nípa ti ara. +Àwọn ẹni tí i ṣe Israẹli; tí àwọn ẹni tí ìsọdọmọ í ṣe, àti ògo, àti májẹ̀mú, àti ìfúnilófin, àti ìsìn Ọlọ́run, àti àwọn ìlérí. Tí ẹni tí àwọn Baba í ṣe, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí Kristi ti wá nípa ti ara, ẹni tí ó borí ohun gbogbo, Ọlọ́run olùbùkún láéláé. Àmín.
+Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di asán. Kì í sá í ṣe gbogbo àwọn tí ó ti inú Israẹli wá, àwọn ni Israẹli. +Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé, nítorí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, gbogbo wọn ni ọmọ. Ní ọ̀nà mìíràn, “Nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀.” +Èyí nì ni pé, kì í ṣe àwọn ọmọ nípa ti ara ni ọmọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìlérí ni a kà ní irú-ọmọ. +Nítorí ọ̀rọ̀ ìlérí ni èyí: “Ní ìwòyí àmọ́dún ni èmi yóò wá, Sara yóò sì ní ọmọ ọkùnrin.”
10 +Kì í sì í ṣe kìkì èyí, ṣùgbọ́n nígbà tí Rebeka pẹ̀lú lóyún fún ẹnìkan, fún Isaaki baba wa. 11 Nítorí nígbà tí kò tí ì bí àwọn ọmọ náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tí ì ṣe rere tàbí búburú—kí ìpinnu Ọlọ́run nípa ti ìyànfẹ́ kí ó lè dúró, 12 +kì í ṣe nípa ti iṣẹ́, bí kò ṣe ti ẹni tí ń peni—a ti sọ fún un pé, “Ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.” 13 +Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Jakọbu ni mo fẹ́ràn, ṣùgbọ́n Esau ni mo kórìíra.”
14 +Ǹjẹ́ àwa yóò ha ti wí? Àìṣòdodo ha wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run bí? Kí a má ri! 15 +Nítorí ó wí fún Mose pé,
“Èmi ó ṣàánú fún ẹni tí èmi yóò ṣàánú fún,
èmi yóò sì ṣe ìyọ́nú fún ẹni tí èmi yóò ṣe ìyọ́nú fún.”
16 Ǹjẹ́ bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ti ẹni tí ó fẹ́, kì í sì í ṣe ti ẹni tí ń sáré, bí kò ṣe ti Ọlọ́run tí ń ṣàánú. 17 +Nítorí ìwé mímọ́ wí fún Farao pé, “Nítorí èyí náà ni mo ṣe gbé ọ dìde, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.” 18 +Nítorí náà ni ó ṣe ń ṣàánú fún ẹni tí ó wù ú, ẹni tí ó wù ú a sì mú ní ọkàn le.
19 Ìwọ ó sì wí fún mi pé, “Kín ni ó ha tún bá ni wí sí? Nítorí ta ni ó ń de ìfẹ́ rẹ lọ́nà?” 20 +Bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ ènìyàn, tà ni ìwọ tí ń dá Ọlọ́run lóhùn? “Ohun tí a mọ, a ha máa wí fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èéṣe tí ìwọ fi mọ mi báyìí?’ ” 21 +Amọ̀kòkò kò ha ni agbára lórí amọ̀, nínú ìṣù kan náà láti ṣe apá kan nínú ohun èlò sí ọlá, àti apá kan nínú ohun èlò sí àìlọ́lá?
22 +Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá fẹ́ fi ìbínú rẹ̀ hàn ń kọ́? Tí ó sì fẹ́ sọ agbára rẹ̀ di mí mọ̀, tí ó sì mú sùúrù púpọ̀ fún àwọn ohun èlò ìbínú tí a ṣe fún ìparun. 23 +Àti kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ ògo rẹ̀ di mí mọ̀ lára àwọn ohun èlò àánú tí ó ti pèsè ṣáájú fún ògo. 24 +Àní àwa, tí ó ti pè, kì í ṣe nínú àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nínú àwọn Kèfèrí pẹ̀lú? 25 +Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé,
“Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ‘ènìyàn mi’,
àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní ‘àyànfẹ́.’ ”
26 +Yóò sì ṣe,
“Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé,
‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’
níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”
27 +Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé:
“Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun,
apá kan ni ó gbàlà.
28 Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé,
yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.”
29 +Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀:
“Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun
ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa,
àwa ìbá ti dàbí Sodomu,
a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.”
30 +Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni. 31 +Ṣùgbọ́n Israẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo. 32 +Nítorí kí ni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni. 33 +Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé,
“Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni
àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú,
ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”
+ 9:3 Ek 32.32. + 9:4 Ro 3.2; 8.15. + 9:6 Ro 2.28-29. + 9:7 Gẹ 21.12; Hb 11.18. + 9:8 Ga 3.29; 4.28. + 9:9 Gẹ 18.10. + 9:10 Gẹ 25.21. + 9:12 Gẹ 25.23. + 9:13 Ml 1.2-3. + 9:14 2Ki 19.7. + 9:15 Ek 33.19. + 9:17 Ek 9.16. + 9:18 Ro 11.7. + 9:20 Isa 29.16; 45.9. + 9:21 2Tm 2.20. + 9:22 Òw 16.4. + 9:23 Ro 8.29. + 9:24 Ro 3.29. + 9:25 Ho 2.23; 1Pt 2.10. + 9:26 Ho 1.10. + 9:27 Isa 10.22-23; Gẹ 22.17; Ho 1.10; Ro 11.5; 2Ọb 19.4; Isa 11.11. + 9:29 Isa 1.9. + 9:30 Ro 3.22; 10.6,20; Ga 2.16; 3.24; Fp 3.9; Hb 11.7. + 9:31 Isa 51.1; Ro 10.2-3; 11.7. + 9:32 1Pt 2.8. + 9:33 Isa 28.16; Ro 10.11.