3
1 Ní orí ibùsùn mi ní òru  
mo wá ẹni tí ọkàn mí fẹ́;  
mo wá a, ṣùgbọ́n èmi kò rí i.   
2 Èmi yóò dìde nísinsin yìí, èmi yóò sì rìn lọ káàkiri ìlú,  
ní àwọn òpópónà àti ní àwọn gbangba òde;  
èmi yóò wá ẹni tí ọkàn mi fẹ́.  
Bẹ́ẹ̀ ni mo wá a ṣùgbọ́n èmi kò rí i.   
3 Àwọn ọdẹ tí ń ṣọ́ ìlú rí mi  
bí wọ́n ṣe ń rìn yíká ìlú.  
“Ǹjẹ́ ìwọ ti rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́?”   
4 Gẹ́rẹ́ tí mo fi wọ́n sílẹ̀  
ni mo rí ẹni tí ọkàn mi fẹ́.  
Mo dìímú, èmi kò sì jẹ́ kí ó lọ  
títí tí mo fi mú u wá sílé ìyá mi,  
sínú yàrá ẹni tí ó lóyún mi.   
5 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,  
mo fi àwọn abo egbin àti abo àgbọ̀nrín igbó fi yín bú  
kí ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè  
kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.   
   
 
6 Ta ni ẹni tí ń ti ijù jáde wá  
bí ọ̀wọ̀n èéfín  
tí a ti fi òjìá àti tùràrí kùn lára  
pẹ̀lú gbogbo ìpara olóòórùn oníṣòwò?   
7 Wò ó! Àkéte rẹ̀ tí í ṣe ti Solomoni,  
àwọn akọni ọgọ́ta ni ó wà yí i ká,  
àwọn akọni Israẹli,   
8 gbogbo wọn ni ó mú idà lọ́wọ́,  
gbogbo wọn ní ìmọ̀ nínú ogun,  
idà oníkálùkù wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,  
wọ́n múra sílẹ̀ fún ìdágìrì òru   
9 Solomoni ọba ṣe àkéte fún ara rẹ̀;  
o fi igi Lebanoni ṣe é.   
10 Ó fi fàdákà ṣe òpó rẹ̀,  
o fi wúrà ṣe ibi ẹ̀yìn rẹ̀.  
Ó fi elése àlùkò ṣe ibùjókòó rẹ̀,  
inú rẹ̀ ni ó ko àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọ̀nyí sí.  
“Pẹ̀lú ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Jerusalẹmu.”   
11 Ẹ jáde wá, ẹ̀yin ọmọbìnrin Sioni,  
kí ẹ sì wo ọba Solomoni tí ó dé adé,  
adé tí ìyá rẹ̀ fi dé e  
ní ọjọ́ ìgbéyàwó rẹ̀,  
ní ọjọ́ ayọ̀ ọkàn rẹ̀.