3
Ìwà àwọn ènìyàn ni ọjọ́ ìkẹyìn
Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀ pé, ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.
Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri. Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. +Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.
Ọ̀rọ̀ ìyànjú Paulu sí Timotiu
10 Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. 11  +Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. 12 Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. 14 Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. 15 Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 16 Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo. 17 Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.
+ 3:8 Ek 7.11. + 3:11 Ap 13.14-52; 14.1-20; 16.1-5.