26
Dafidi da ẹ̀mí Saulu sí lẹ́ẹ̀kejì
1Sa 24.1-22.Nígbà náà ni àwọn ará Sifi tọ Saulu wá sí Gibeah, wọn wí pé, “Dafidi kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hakila, èyí tí ó wà níwájú Jeṣimoni?”
Saulu sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sifi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àṣàyàn ènìyàn ni Israẹli sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dafidi ni ijù Sifi. Saulu sì pàgọ́ rẹ̀ ní ibi òkè Hakila tí o wà níwájú Jeṣimoni lójú ọ̀nà, Dafidi sì jókòó ni ibi ijù náà, ó sì rí pé Saulu ń tẹ̀lé òun ni ijù náà. Dafidi sì rán ayọ́lẹ̀wò jáde, ó sì mọ nítòótọ́ pé Saulu ń bọ̀.
Dafidi sì dìde, ó sì wá sí ibi ti Saulu pàgọ́ sí: Dafidi rí ibi tí Saulu gbé dùbúlẹ̀ sí, àti Abneri ọmọ Neri, olórí ogun rẹ̀: Saulu sì dùbúlẹ̀ láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, àwọn ènìyàn náà sì pàgọ́ wọn yí i ká.
Dafidi sì dáhùn, ó sì wí fún Ahimeleki, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hiti, àti fún Abiṣai ọmọ Seruiah ẹ̀gbọ́n Joabu, pé, “Ta ni yóò ba mi sọ̀kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Saulu ni ibùdó?”
Abiṣai sì wí pé, “Èmi yóò ba ọ sọ̀kalẹ̀ lọ.”
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi àti Abiṣai sì tọ àwọn ènìyàn náà wá lóru: sì wò ó, Saulu dùbúlẹ̀ ó sì ń sùn láàrín kẹ̀kẹ́, a sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ni ibi tìmùtìmù rẹ̀: Abneri àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká.
Abiṣai sì wí fún Dafidi pé, “Ọlọ́run ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ lónìí: ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, sá à jẹ́ kí èmi o fi ọ̀kọ̀ gún un mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, èmi kì yóò gun un lẹ́ẹ̀méjì.”
Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Má ṣe pa á nítorí pé ta ni lè na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró Olúwa kí ó sì wà láìjẹ̀bi?” 10 Dafidi sì wí pé, “Bí Olúwa tí ń bẹ Olúwa yóò pa á, tàbí ọjọ́ rẹ̀ yóò sì pé tí yóò kú, tàbí òun ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibi ìjà yóò sì ṣègbé níbẹ̀. 11 Olúwa má jẹ́ kí èmi na ọwọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa. Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, mú ọ̀kọ̀ náà tí ń bẹ níbi tìmùtìmù rẹ̀, àti ìgò omi kí a sì máa lọ.”
12 Dafidi sì mú ọ̀kọ̀ náà àti ìgò omi náà kúrò níbi tìmùtìmù Saulu: wọ́n sì bá tiwọn lọ, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí i, tàbí tí ó mọ̀: kò sì sí ẹnìkan tí ó jí; gbogbo wọn sì sùn; nítorí pé oorun èjìká láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá ti ṣubú lù wọ́n.
13 Dafidi sì rékọjá sí ìhà kejì, ó sì dúró lórí òkè kan tí ó jìnnà réré; àlàfo kan sì wà láàrín méjì wọn. 14 Dafidi sì kọ sí àwọn ènìyàn náà àti sí Abneri ọmọ Neri wí pé, “Ìwọ kò dáhùn, Abneri?”
Nígbà náà ni Abneri sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ta ni ń pe ọba?”
15 Dafidi sì wí fún Abneri pé, “Alágbára ọkùnrin kọ́ ni ìwọ bí? Ta ni ó sì dàbí ìwọ ni Israẹli? Ǹjẹ́ èéṣe tí ìwọ kò tọ́jú ọba Olúwa rẹ? Nítorí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn náà ti wọlé wá láti pa ọba olúwa rẹ. 16 Nǹkan tí ìwọ ṣe yìí kò dára. Bí Olúwa ti ń bẹ, o tọ́ kí ẹ̀yin ó kú, nítorí pé ẹ̀yin kò pa olúwa yín mọ́, ẹni àmì òróró Olúwa. Ǹjẹ́ sì wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba gbé wà, àti ìgò omi tí ó ti wà níbi tìmùtìmù rẹ̀.”
17 Saulu sì mọ ohùn Dafidi, ó sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí Dafidi ọmọ mi?”
Dafidi sì wí pé, “Ohùn mi ni, olúwa mi, ọba.” 18 Òun sì wí pé, “Nítorí kín ni olúwa mi ṣe ń lépa ìránṣẹ́ rẹ̀? Kín ni èmi ṣe? Tàbí ìwà búburú wo ni ó wà lọ́wọ́ mi. 19 Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, olúwa mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Bí ó bá ṣe Olúwa bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ; ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú Olúwa; nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má ba à ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní Olúwa, wí pé, ‘Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn.’ 20 Ǹjẹ́ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ mi ó sàn sílẹ̀ níwájú Olúwa; nítorí ọba Israẹli jáde láti wá ẹ̀mí mi bi ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè ńlá.”
21 Saulu sì wí pé, “Èmi ti dẹ́ṣẹ̀: yípadà, Dafidi ọmọ mi: nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe iyebíye lójú rẹ lónìí: wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ.”
22 Dafidi sì dáhùn, ó sì wí pé, “Wò ó, ọ̀kọ̀ ọba! Kí ó sì jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rékọjá wá gbà á. 23 Olúwa o san án fún olúkúlùkù bí òdodo rẹ̀ àti bí òtítọ́ rẹ̀: nítorí pé Olúwa tí fi ọ lé mi lọ́wọ́ lónìí, ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ nawọ́ mi sí ẹni àmì òróró Olúwa. 24 Sì wò ó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí rẹ ti tóbi lónìí lójú mi, bẹ́ẹ̀ ni ki ẹ̀mí mi ó tóbi lójú Olúwa, kí ó sì gbà mí lọ́wọ́ ibi gbogbo.”
25 Saulu sì wí fún Dafidi pé, “Alábùkún fún ni ìwọ, Dafidi ọmọ mi: nítòótọ́ ìwọ yóò sì ṣe nǹkan ńlá, nítòótọ́ ìwọ yóò sì borí.”
Dafidi sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, Saulu sì yípadà sí ibùgbé rẹ̀.

26:1 1Sa 24.1-22.