26
Ussiah ọba Juda
1 2Ọb 14.21,22; 15.2,3.Nígbà náà gbogbo ènìyàn Juda mú Ussiah, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Amasiah. 2 Òun ni ẹni náà tí ó tún Elati kọ́, ó sì mú padà sí Juda lẹ́yìn ìgbà tí Amasiah ọba ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.
3 Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláàádọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoliah; ó sì wá láti Jerusalẹmu. 4 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe. 5 Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ Sekariah, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ́n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa, Ọlọ́run fún un ní ohun rere.
6 Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú Filistini ó sì wó odi Gati lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará Filistini. 7 Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni. 8 Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá.
9 Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le 10 Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.
11 Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba. 12 Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600). 13 Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀. 14 Ussiah sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun. 15 Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.
16 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ussiah jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. 17 Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lé e. 18 Wọ́n sì takò ọba Ussiah, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.”
19 Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀. 20 2Ọb 15.5-7.Nígbà tí Asariah olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì rí i wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lúpẹ̀lú, òun tìkára rẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí Olúwa ti kọlù ú.
21 Ọba Ussiah sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé àwọn adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ilé Olúwa. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.
22 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ussiah láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ láti ọwọ́ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. 23 Ussiah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba, rẹ̀ a sì sin sí ẹ̀gbẹ́ wọn nínú oko ìsìnkú fún ti iṣẹ́ tí àwọn ọba, nítorí àwọn ènìyàn wí pé “Ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀,” Jotamu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.