12
Natani bá Dafidi wí
Olúwa sì rán Natani sí Dafidi òun sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin méjì ń bẹ ní ìlú kan; ọ̀kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, èkejì sì jẹ́ tálákà. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà sì ní àgùntàn àti màlúù lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tálákà náà kò sì ní nǹkan bí kò ṣe àgùntàn kékeré kan èyí tí ó sì ń tọ́, ó sì dàgbà ní ọwọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀; a máa jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀, a sí máa mu nínú ago rẹ̀, a sì máa dùbúlẹ̀ ní àyà rẹ̀, ó sì dàbí ọmọbìnrin kan fún un.
“Àlejò kan sì tọ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wá, òun kò sì fẹ́ mú nínú àgùntàn rẹ̀, àti nínú màlúù rẹ̀, láti fi ṣe àlejò fún ẹni tí ó tọ̀ ọ́ wá, o sì mú àgùntàn ọkùnrin tálákà náà fi ṣe àlejò fún ọkùnrin tí ó tọ̀ ọ́ wá.”
Ìbínú Dafidi sì ru gidigidi sí ọkùnrin náà; ó sì wí fún Natani pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láààyè, ọkùnrin náà tí ó ṣe nǹkan yìí, kíkú ni yóò kú. Òun yóò sì san àgùntàn náà padà ní mẹ́rin mẹ́rin, nítorí tí ó ṣe nǹkan yìí àti nítorí tí kò ní àánú.”
Natani sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà. Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Èmi fi ọ́ jẹ ọba lórí Israẹli, èmi sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Saulu. Èmi sì fi ilé olúwa rẹ fún ọ, àti àwọn obìnrin olúwa rẹ sí àyà rẹ, èmi sì fi ìdílé Israẹli àti ti Juda fún ọ; tí àwọn wọ̀nyí bá sì kéré jù fún ọ èmi ìbá sì fún ọ sí i jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Uriah ará Hiti, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ammoni pa á. 10 Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúrò ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Uriah ará Hiti láti ṣe aya rẹ.’
11 “Báyìí ni Olúwa wí, kíyèsi i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládùúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrùn yìí. 12 Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Israẹli, àti níwájú òòrùn.’ ”
13 Dafidi sì wí fún Natani pé, “Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa!”
Natani sì wí fún Dafidi pé, “Olúwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú. 14 Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀tá Olúwa láti sọ ọ̀rọ̀-òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.”
Ọmọ náà kú
15 Natani sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi ààrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Uriah bí fún Dafidi, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀. 16 Dafidi sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dafidi sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dùbúlẹ̀ lórí ilé ni òru náà. 17 Àwọn àgbàgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé, ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.
18 Ní ọjọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dafidi sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsi i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní èṣe tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”
19 Nígbà tí Dafidi sì rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, Dafidi sì kíyèsi i, pé ọmọ náà kú, Dafidi sì béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ọmọ náà kú bí?”
Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Ó kú.”
20 Dafidi sì dìde ní ilẹ̀, ó sì wẹ̀, ó fi òróró pa ara, ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó sì wọ inú ilé Olúwa lọ, ó sì wólẹ̀ sin, ó sì wá sí ilé rẹ̀ ó sì béèrè, wọ́n sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì jẹun.
21 Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láààyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sọkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”
22 Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láààyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sọkún: nítorí tí èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀? Bí Olúwa ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’ 23 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”
Batṣeba sì tún bí ọmọ mìíràn tí a pè ní Solomoni
24 Dafidi sì ṣìpẹ̀ fún Batṣeba aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀, òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dafidi sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Solomoni, Olúwa sì fẹ́ ẹ. 25 Ó sì rán Natani wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jedidiah, nítorí Olúwa.
Ìṣẹ́gun Dafidi lórí àwọn Ammoni
26 1Ki 20.1-3.Joabu sì bá Rabba ti àwọn ọmọ Ammoni jagun, ó sì gba ìlú ọba wọn. 27 Joabu sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti bá Rabba jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olómi. 28 Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má bá à gba ìlú náà kí a má ba à pè é ní orúkọ mi.”
29 Dafidi sì kó gbogbo ènìyàn náà jọ, sí Rabba, ó sì bá a jà, ó sì gbà á. 30 Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ tálẹ́ǹtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dafidi lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀. 31 Ó sì kó àwọn ènìyàn náà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ ayùn, àti sí iṣẹ́ nǹkan ìtulẹ̀ tí a fi irin ṣe, àti sí iṣẹ́ àáké irin, ó sì fi wọ́n sí iṣẹ́ bíríkì ṣíṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni òun sì ṣe sí gbogbo ìlú àwọn ọmọ Ammoni. Dafidi àti gbogbo àwọn ènìyàn náà sì padà sí Jerusalẹmu.

12:26 1Ki 20.1-3.