5
Wò mí kí o sì yè
Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Israẹli, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ:
“Wúńdíá Israẹli ṣubú
láì kò sì le padà dìde
ó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀
kò sí ẹni tí yóò gbé e dìde.”
Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:
“Ìlú tí ẹgbẹ̀rún (1,000) alágbára ti jáde,
yóò dín ku ọgọ́rùn-ún ní Israẹli.
Ìlú tí ọgọ́rùn-ún alàgbà ti jáde
yóò ṣẹ́kù ẹni mẹ́wàá.”
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Israẹli:
“Wá mi kí o sì yè;
ẹ má ṣe wá Beteli,
ẹ má ṣe lọ sí Gilgali,
ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba.
Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn,
A ó sì sọ Beteli di asán.”
Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè,
kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu
a sì jó o run
Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.
 
Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò
tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.
 
Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni
ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀
tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀
ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀
tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀
Olúwa ni orúkọ rẹ̀,
Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi
tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.
 
10 Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè
ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.
 
11 Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀
o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn.
Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé
ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn,
Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.
Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn.
12 Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ
mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.
 
Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀
o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.
13 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí,
nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.
 
14 Wá rere, má ṣe wá búburú
kí ìwọ ba à le yè.
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ.
Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí.
15 Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere
dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́
bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára
yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.
16 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà
igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú.
A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún
àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún.
17 Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà,
nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,”
ni Olúwa wí.
Ọjọ́ Olúwa
18 Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́
nítorí ọjọ́ Olúwa
kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa?
Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́.
19 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún,
tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.
Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ
tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀
tí ejò sì bù ú ṣán.
20 Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?
Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀.
 
21 “Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín,
Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín.
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá.
Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.
Èmi kò ní náání wọn.
23 Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn!
Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.
24 Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò
àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!
 
25 Ap 7.42-43.“Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá
ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?
26 Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè,
ibùgbé àwọn òrìṣà yín,
àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,
èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.
27 Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,”
ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.

5:25 Ap 7.42-43.