31
Besaleli àti Oholiabu
Ek 35.30–36.1.Olúwa wí fún Mose pé, “Wò ó, Èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, Èmi sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́.
 
“Bákan náà, Èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ:
 
“àgọ́ àjọ náà,
àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀,
àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà,
tábìlì àti ohun èlò rẹ̀,
ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,
pẹpẹ tùràrí,
pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,
agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀,
10 àti aṣọ híhun pẹ̀lú,
papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà
àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà,
11 òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún Ibi Mímọ́.
 
“Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.”
Ọjọ́ ìsinmi
12 Ek 20.8; 23.12; 35.2; De 5.12-15.Olúwa wí fún Mose pé, 13 “Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.
14 “ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ. 15 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́. 16 Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé. 17 Yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”
18 Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ sísọ fún Mose lórí òkè Sinai, ó fún un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, òkúta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.

31:1 Ek 35.30–36.1.

31:12 Ek 20.8; 23.12; 35.2; De 5.12-15.