8
Ìbọ̀rìṣà nínú ilé Olúwa
1 Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹfà ọdún kẹfà bí mo ṣe jókòó nílé mi pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Juda níwájú mi, ọwọ́ Olúwa Olódùmarè bà lé mi níbẹ̀. 2 Nígbà tí mo wò, mo rí ohun kan tí ó jọ ènìyàn. Láti ibi ìbàdí rẹ lọ sísàlẹ̀ dàbí iná, láti ibi ìbàdí yìí sókè sì mọ́lẹ̀ bí idẹ tó ń kọ mọ̀nà. 3 Ó na ohun tó dàbí ọwọ́ jáde, ó fi gba mi ní irun orí mú, Ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede-méjì ayé àti ọ̀run, ó sì mú mi lọ rí ìran Ọlọ́run, mo sì lọ sí Jerusalẹmu, ṣí ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà òde àríwá níbi tí ère owú tí ó ń mú ni bínú wá níwájú mi. 4 Sì kíyèsi i, ògo Ọlọ́run Israẹli wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìran ti mo rí ni pẹ̀tẹ́lẹ̀.
5 Ó sì sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbójú sókè sí ìhà àríwá.” Èmi náà sì gbójú sókè sí ìhà àríwá mo sì rí ère tí ó ń mú ni jowú ní ẹnu-ọ̀nà ibi pẹpẹ.
6 Ó sì wí fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o rí ohun tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra ńlá tí ilé Israẹli ń ṣe, láti lé mi jìnnà réré sí ibi mímọ́ mi? Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tún rí àwọn ìríra ńlá tó tóbi jù èyí lọ.”
7 Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá. Mo wò ó, mo sì rí ihò kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri. 8 Nígbà náà ló sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, gbẹ́ inú ògiri náà,” nígbà tí mo sì gbẹ́ inú ògiri, mo rí ìlẹ̀kùn kan.
9 Ó sì wí fún mi pé, “Wọlé kí ìwọ kí ó rí ohun ìríra búburú tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.” 10 Mo wọlé, mo sì rí àwòrán oríṣìíríṣìí ẹranko tí ń fà nílẹ̀ àti àwọn ẹranko ìríra àti gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n yà sára ògiri. 11 Níwájú wọn ni àádọ́rin ọkùnrin tó jẹ́ àgbàgbà ilé Israẹli dúró sí, Jaaṣaniah ọmọ Ṣafani sì dúró sí àárín wọn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì mú àwo tùràrí lọ́wọ́, òórùn sì ń tú jáde.
12 Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, ṣé o ti rí ohun tí àwọn àgbàgbà ilé Israẹli ń ṣe nínú òkùnkùn, olúkúlùkù ní yàrá òrìṣà rẹ̀? Wọ́n ní, ‘Olúwa kò rí wa; Olúwa ti kọ̀ ilé náà sílẹ̀.’ ” 13 Ó tún sọ fún mi pé, “Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe àwọn ohun ìríra tó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ.”
14 Ó mú mi wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sí ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tó wà ní ìhà àríwá, mo sì rí àwọn obìnrin tó jókòó, tí wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ fún Tamusi. 15 Ó sọ fún mi pé, “Ṣé ìwọ rí báyìí, ọmọ ènìyàn? Ìwọ yóò tún rí ìríra tó ga jù èyí lọ.”
16 Ó mú mi wá sí ibi àgbàlá ilé Olúwa, ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili Olúwa, láàrín ìloro àti pẹpẹ, ni ìwọ̀n ọkùnrin mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (25) wà, tí wọ́n kẹ́yìn sí tẹmpili Olúwa tí wọn sì kọjú sí ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún oòrùn ní apá ìlà-oòrùn.
17 Ó sì wí fún mi, “Ṣé ìwọ ti rí èyí ọmọ ènìyàn? Ǹjẹ́ ohun kékeré ni fún ilé Juda láti ṣe àwọn ohun ìríra tí wọn ń ṣe níbi yìí? Ṣé o tún yẹ kí wọ́n fi ìwà ipá kún ilẹ̀ kí wọn sì máa mú mi bínú ní gbogbo ìgbà? Wò wọn bi wọn ṣe n fi ẹ̀ka wọn sínú inú wọn. 18 Nítorí náà, èmi yóò fi ìbínú bá wọn wí; èmi kò ní i dá wọn sí bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì ní fojú àánú wò wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ ń pariwo sí mi létí, èmi kò ní fetí sí wọn.”