13
Ìpinyà Abramu àti Lọti
Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.
Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai. Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.
Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.
Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.”
10 Gẹ 2.10.Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.) 11 Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. 12 Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú Olúwa.
14 Olúwa sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. 15 Ap 7.5; Ga 3.16.Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé. 16 Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. 17 Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.”
18 Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.

13:10 Gẹ 2.10.

13:15 Ap 7.5; Ga 3.16.