32
Jakọbu gbáradì láti pàdé Esau
Jakọbu sì ń bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ, àwọn angẹli Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀. Nígbà tí Jakọbu rí wọn, ó wí pé, “Àgọ́ Ọlọ́run ni èyí!” Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ni Mahanaimu.
Jakọbu sì rán àwọn oníṣẹ́ ṣáájú ara rẹ̀ sí Esau arákùnrin rẹ̀ ni ilẹ̀ Seiri ní orílẹ̀-èdè Edomu. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò wí fún Esau olúwa mi, Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ wí pé, ‘Mo ti ṣe àtìpó lọ́dọ̀ Labani títí ó fi di àsìkò yìí. Mo ní màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àti ewúrẹ́. Mo tún ni àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin. Mo ń ránṣẹ́ yìí sí olúwa mi kí èmi le è rí ojúrere rẹ.’ ”
Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ náà padà tọ Jakọbu wà, wọ́n wí pé “Esau arákùnrin rẹ ti múra láti wá pàdé rẹ pẹ̀lú irinwó (400) ọkùnrin.”
Pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìbànújẹ́ ni Jakọbu fi pín àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sí ìpín méjì, ó sì pín àwọn ẹran ọ̀sìn, agbo ẹran àti ìbákasẹ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí ó rò ó nínú rẹ̀ pé, “Bí Esau bá kọjú ogun sí ìpín kan, ìpín kejì yóò sá àsálà.”
Nígbà náà ni Jakọbu gbàdúrà pe, “Ọlọ́run Abrahamu baba mi, àti Ọlọ́run Isaaki baba mi, Olúwa tí ó wí fún mi pé, ‘Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere,’ 10 èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fihàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jordani yìí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì. 11 Jọ̀wọ́ Olúwa gbà mí lọ́wọ́ Esau arákùnrin mi, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé yóò wá dojú ìjà kọ mí àti àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ mi. 12 Gẹ 22.17.Ṣùgbọ́n ìwọ ti ṣèlérí pé, ‘Èmi yóò mú ọ gbilẹ̀, èmi yóò sì mú kí àwọn ìran rẹ dà bì í yanrìn òkun tí ẹnikẹ́ni kò le è kà.’ ”
13 Ó sì lo òru ọjọ́ náà níbẹ̀. Ó mú ẹ̀bùn fún Esau arákùnrin rẹ̀ nínú ohun ìní rẹ̀. 14 Igba ewúrẹ́, ogún òbúkọ, igba àgùntàn, ogún àgbò, 15 ọgbọ̀n abo ìbákasẹ pẹ̀lú ọmọ wọn, ogójì abo màlúù àti akọ màlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mẹ́wàá. 16 Ó sì fi wọ́n lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrín ọ̀wọ́ agbo ẹran kọ̀ọ̀kan sí èkejì.”
17 Ó pàṣẹ fún èyí tí ó ṣáájú pé, “Nígbà tí arákùnrin mi Esau bá pàdé rẹ tí ó sì béèrè ẹni tí ìwọ í ṣe àti ibi tí ìwọ ń lọ àti ẹni tí ó ni agbo ẹran tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ, 18 nígbà náà ni ìwọ yóò wí pé, ‘Ti ìránṣẹ́ rẹ Jakọbu ni wọ́n. Ẹ̀bùn ni ó sì fi wọ́n ṣe fún Esau olúwa mi, òun pàápàá ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ”
19 Jakọbu sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ fún ọ̀wọ́ kejì àti ẹ̀kẹta àti àwọn tókù tí ó tẹ̀lé agbo ẹran pé, “Ohun kan ṣoṣo yìí náà ni kí ẹ sọ fún Esau nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀. 20 Kí ẹ rí i dájú wí pé, ẹ sọ fún un pé, ‘Jakọbu ìránṣẹ́ rẹ̀ ń bọ̀ lẹ́yìn wa.’ ” Èrò Jakọbu ni láti fi àwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí tu Esau lójú pé bóyá inú Esau yóò dùn sí òun nígbà tí àwọn bá pàdé. 21 Nítorí náà ẹ̀bùn Jakọbu ṣáájú rẹ̀ lọ, Jakọbu pàápàá sì lo òru ọjọ́ náà nínú àgọ́.
Jakọbu bá Ọlọ́run ja ìjàkadì
22 Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jabbok. 23 Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè odò, ó sì rán àwọn ohun ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú. 24 Ho 12.3,4.Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. 25 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì. 26 Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.”
Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”
27 Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀.
Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.”
28 Gẹ 35.10.Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”
29 On 13.17,18.Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.”
Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀.
30 Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”
31 Bí ó sì ti ń kọjá Penieli, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀. 32 Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kì í fi í jẹ iṣan tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀ títí di òní olónìí, nítorí níbi iṣan náà ni a ti fọwọ́ kan ibi tí egungun itan Jakọbu ti bẹ̀rẹ̀.

32:12 Gẹ 22.17.

32:24 Ho 12.3,4.

32:28 Gẹ 35.10.

32:29 On 13.17,18.