14
Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jakọbu,
yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i
yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn.
Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn,
wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu.
Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n
wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn.
Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè
gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin
ní ilẹ̀ Olúwa.
Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn
wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn.
Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé,
báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!
Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!
Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,
ọ̀pá àwọn aláṣẹ,
èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀
pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,
nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè
pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.
Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,
wọ́n bú sí orin.
Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn
igi kedari ti Lebanoni
ń yọ̀ lórí rẹ wí pé,
“Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,
kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”
 
Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè
láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀
ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ
gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé
ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn
gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Gbogbo wọn yóò dáhùn,
wọn yóò wí fún ọ wí pé,
“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú
ìwọ náà ti dàbí wa.”
11 Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,
pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ,
àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ
àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.
 
12 Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá,
ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!
A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé,
ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!
13 Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,
“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;
èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè
ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,
Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ
ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.
14 Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀;
èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”
15 Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ
lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.
 
16 Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,
wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:
“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì
tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
17 Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù,
tí ó sì pa ìlú ńlá ńlá rẹ̀ run
tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?”
 
18 Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀
ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀,
àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,
àwọn tí idà ti gún,
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.
Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀,
20 a kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn,
nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́
o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.
 
 
Ìran àwọn ìkà
ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.
21 Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ
nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn,
wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀
kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn.
 
22 “Èmi yóò dìde sókè sí wọn,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà,
àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
23 Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí
àti sí irà;
Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Asiria
24 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,
“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,
àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.
25 Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi,
ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.
Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,
ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.”
 
26 Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,
èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè.
27 Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,
ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?
Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì àwọn Filistini
28 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú.
29 Jr 47; El 25.15-17; Jl 3.4-8; Am 1.6-8; Sf 2.4-7; Sk 9.5-7.Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia,
pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;
láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀
yóò ti hù jáde,
èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.
30 Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,
àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.
Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun,
yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.
 
31 Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, ìwọ ìlú!
Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia!
Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá,
kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.
32 Kí ni ìdáhùn tí a ó fún
agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà?
Olúwa ti fi ìdí Sioni kalẹ̀,
àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí
a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”

14:29 Jr 47; El 25.15-17; Jl 3.4-8; Am 1.6-8; Sf 2.4-7; Sk 9.5-7.