45
1 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀,
sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú
láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀
àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn,
láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀
tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.
2 Èmi yóò lọ síwájú rẹ,
Èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ
Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ
èmi ó sì gé ọ̀pá irin.
3 Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin,
tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa,
Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.
4 Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi
àti Israẹli ẹni tí mo yàn,
Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,
mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
5 Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn;
yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,
Èmi yóò fún ọ ní okun,
bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn
títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀
kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.
Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.
7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn,
Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù;
Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;
jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,
jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,
jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;
Èmi Olúwa ni ó ti dá a.
9 Isa 29.16; Ro 9.20.“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,
ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.
Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:
‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,
‘Òun kò ní ọwọ́?’
10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,
‘Kí ni o bí?’
tàbí sí ìyá rẹ̀,
‘Kí ni ìwọ ti bí?’
11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí,
Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
Nípa ohun tí ó ń bọ̀,
ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,
tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé
tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.
Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run;
mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta.
13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi.
Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.
Òun yóò tún ìlú mi kọ́
yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
“Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi,
àti àwọn Sabeani—
wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ
wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;
wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,
wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.
Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,
wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,
‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn;
kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,
Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli,
16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì
wọn yóò sì kan àbùkù;
gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.
pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;
a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín,
títí ayé àìnípẹ̀kun.
18 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí,
ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run,
Òun ni Ọlọ́run;
ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé,
Òun ló ṣe é;
Òun kò dá a láti wà lófo,
ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀,
Òun wí pé:
“Èmi ni Olúwa,
kò sì ṣí ẹlòmíràn.
19 Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin,
láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn,
Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé,
‘Ẹ wá mi lórí asán.’
Èmi Olúwa sọ òtítọ́,
Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
20 “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá;
ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn orílẹ̀-èdè wá.
Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri,
tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.
21 Ap 15.18.Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá,
jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.
Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,
ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?
Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa?
Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,
Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;
kò sí ẹlòmíràn àfi èmi.
22 “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,
ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé;
nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
23 Ro 14.11; Fp 2.10-11.Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra,
ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi,
ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́.
Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;
nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
24 Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni
òdodo àti agbára wà.’ ”
Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;
yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.
25 Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Israẹli
ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.