48
Israẹli olórí kunkun
“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu,
ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli
tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda,
ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa
tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli
ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo,
ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì
tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli—
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́,
ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀;
lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.
Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó;
àwọn iṣan ọrùn yín sì jẹ́ irin;
bẹ́ẹ̀ ni iwájú yín idẹ ni.
Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ
ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín
tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,
‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;
àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’
Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn.
Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí?
 
“Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọ
fún ọ nípa nǹkan tuntun,
àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀.
A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́
ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.
Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,
‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’
Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí
láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.
Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;
a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.
Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;
nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
kí a má ba à ké ọ kúrò.
10 Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé
kì í ṣe bí i fàdákà;
Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.
11 Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí.
Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.
Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.
Israẹli dòmìnira
12 Isa 44.6; If 1.17; 2.8; 22.13.“Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu
Israẹli ẹni tí mo pè.
Èmi ni ẹni náà;
Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
13 Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;
nígbà tí mo pè wọ́n,
gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.
 
14 “Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́.
Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí.
Olúwa ti fẹ́ ẹ,
yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni,
apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.
15 Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.
Èmi yóò mú un wá,
òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.
16 “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:
“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;
ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”
 
Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi,
pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.
 
17 Èyí ni ohun tí Olúwa wí,
Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,
tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.
18 Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,
àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,
àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.
19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,
àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;
orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò
tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”
 
20 Fi Babeli sílẹ̀,
sá fún àwọn ará Babeli,
ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀
kí o sì kéde rẹ̀.
Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;
wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
21 Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn
kọjá nínú aginjù;
ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;
ó fọ́ àpáta
omi sì tú jáde.
 
22 “Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí,
“Fún àwọn ìkà.”

48:12 Isa 44.6; If 1.17; 2.8; 22.13.