50
Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli àti ìgbọ́ràn ìránṣẹ́
Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà
èyí tí mo fi lé e lọ?
Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi
ni mo tà ọ́ fún?
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́;
nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.
Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan?
Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn?
Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́?
Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí?
Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun,
Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀;
àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi
wọ́n sì kú fún òǹgbẹ.
Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀
mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”
 
Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,
láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.
O jí mi láràárọ̀,
o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;
Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,
àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi;
Èmi kò fi ojú mi pamọ́
kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.
Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́,
a kì yóò dójútì mí.
Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ
èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí.
Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí?
Jẹ́ kí a kojú ara wa!
Ta ni olùfisùn mi?
Jẹ́ kí ó kò mí lójú!
Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.
Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi?
Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;
kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.
 
10 Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa
tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu?
Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn
tí kò ní ìmọ́lẹ̀,
kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa
kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná
tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín,
ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín,
àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá.
Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá.
Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.