56
Ìgbàlà fún àwọn mìíràn
1 Èyí ni ohun ti Olúwa sọ:
“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́
ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,
nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí
àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.
2 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,
àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin,
tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́,
tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”
3 Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀
mọ́ Olúwa sọ wí pé,
“Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé,
“Igi gbígbẹ lásán ni mí.”
4 Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí:
“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,
tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi
tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin
5 fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀
ìrántí kan àti orúkọ kan
tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin,
Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé
tí a kì yóò ké kúrò.
6 Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa
láti sìn ín,
láti fẹ́ orúkọ Olúwa
àti láti foríbalẹ̀ fún un
gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́
àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—
7 Mt 21.13; Mk 11.17; Lk 19.46.àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi,
èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.
Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn,
ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi;
nítorí a ó máa pe ilé mi ní
ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”
8 Olúwa Olódùmarè sọ wí pé—
ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ:
“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn
yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”
Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan àwọn ìkà
9 Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá,
ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!
10 Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú,
gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀;
gbogbo wọn jẹ́ adití ajá,
wọn kò lè gbó;
wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá,
wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.
11 Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀;
wọn kì í ní ànító.
Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye;
olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀,
ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.
12 Igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ni wí pé, “Wá, fún mi ní ọtí wáìnì!
Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yó
ọ̀la yóò sì dàbí òní,
tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”